Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 11:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI nwọn si sunmọ eti Jerusalemu, leti Betfage ati Betani, li òke Olifi, o rán meji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀,

2. O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si iletò ti o kọju si nyin: lojukanna bi ẹnyin ti nwọ̀ inu rẹ̀ lọ, ẹnyin ó si ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ kan ti a so, ti ẹnikẹni ko gùn rì; ẹ tú u, ki é si fà a wá.

3. Bi ẹnikẹni ba si wi fun nyin pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe eyi? ẹ wipe, Oluwa ni fi ṣe; lojukanna yio si rán a wá sihinyi.

4. Nwọn si mu ọ̀na wọn pọ̀n, nwọn ri ọmọ kẹtẹkẹtẹ na ti a so li ẹnu-ọ̀na lode ni ita gbangba; nwọn si tú u.

Ka pipe ipin Mak 11