Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mak 10:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si dide kuro nibẹ̀, o si wá si ẹkùn Judea niha oke odò Jordani: awọn enia si tún tọ̀ ọ wá; bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si tún nkọ́ wọn.

2. Awọn Farisi si tọ̀ ọ wá, nwọn ndán a wò, nwọn si bi i lẽre, wipe, O tọ́ fun ọkunrin ki o fi aya rẹ̀ silẹ?

3. O si dahùn o si wi fun wọn pe, Aṣẹ kini Mose pa fun nyin?

4. Nwọn si wipe, Mose yọda fun wa lati kọ iwe ikọsilẹ fun u, ki a si fi i silẹ.

5. Jesu si da wọn lohùn, o si wi fun wọn pe, Nitori lile àiya nyin li o ṣe kọ irú ofin yi fun nyin.

6. Ṣugbọn lati igba ti aiye ti ṣẹ, Ọlọrun da wọn ti akọ ti abo.

7. Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ ti yio si faramọ aya rẹ̀;

8. Awọn mejeji a si di ara kan: nitorina nwọn kì iṣe meji mọ́, bikoṣe ara kan.

9. Nitorina ohun ti Ọlọrun ba so ṣọkan, ki enia ki o máṣe yà wọn.

10. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tun bi i lẽre ọ̀ran kanna ninu ile.

11. O si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba fi aya rẹ̀ silẹ, ti o ba si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga si i.

Ka pipe ipin Mak 10