Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luk 1:53-68 Yorùbá Bibeli (YCE)

53. O ti fi ohun ti o dara kún awọn ti ebi npa; o si rán awọn ọlọrọ̀ pada lọwọ ofo.

54. O ti ràn Israeli ọmọ-ọdọ rẹ̀ lọwọ, ni iranti ãnu rẹ̀;

55. Bi o ti sọ fun awọn baba wa, fun Abrahamu, ati fun irú-ọmọ rẹ̀ lailai.

56. Maria si ba a joko niwọn oṣù mẹta, o si pada lọ si ile rẹ̀.

57. Ọjọ Elisabeti pe wayi ti yio bí; o si bí ọmọkunrin kan.

58. Ati awọn aladugbo, ati awọn ibatan rẹ̀ gbọ́ bi Oluwa ti ṣe ãnu nla fun u; nwọn si ba a yọ̀.

59. O si ṣe, ni ijọ kẹjọ nwọn wá lati kọ ọmọ na nila; nwọn si sọ orukọ rẹ̀ ni Sakariah, gẹgẹ bi orukọ baba rẹ̀.

60. Iya rẹ̀ si dahùn, o ni Bẹ̃kọ; bikoṣe Johanu li a o pè e.

61. Nwọn si wi fun u pe, Kò si ọkan ninu awọn ará rẹ ti a npè li orukọ yi.

62. Nwọn si ṣe apẹrẹ si baba rẹ̀, bi o ti nfẹ ki a pè e.

63. O si bère walã, o kọ, wipe, Johanu li orukọ rẹ̀. Ẹnu si yà gbogbo wọn.

64. Ẹnu rẹ̀ si ṣí lọgan, okùn ahọn rẹ̀ si tú, o si sọ̀rọ, o si nyìn Ọlọrun.

65. Ẹ̀ru si ba gbogbo awọn ti mbẹ li àgbegbe wọn: a si rohin gbogbo nkan wọnyi ká gbogbo ilẹ òke Judea.

66. Gbogbo awọn ti o gbọ́ si tò o sinu ọkàn wọn, nwọn nwipe, Irú ọmọ kili eyi yio jẹ! Ọwọ́ Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.

67. Sakariah baba rẹ̀ si kún fun Ẹmí Mimọ́, o si sọtẹlẹ, o ni,

68. Olubukun li Oluwa Ọlọrun Israeli; nitoriti o ti bojuwò, ti o si ti dá awọn enia rẹ̀ nide,

Ka pipe ipin Luk 1