Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Luk 1:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIWỌNBI ọ̀pọ enia ti dawọle e lati tò ìhin wọnni jọ lẹsẹsẹ, eyiti o ti gbilẹ ṣinṣin lãrin wa,

2. Ani gẹgẹ bi awọn ti o ṣe oju wọn lati ibẹrẹ, ti nwọn si jasi iranṣẹ ọrọ na, ti fi le wa lọwọ;

3. O si yẹ fun mi pẹlu, lati kọwe si ọ lẹsẹsẹ bi mo ti wadi ohun gbogbo kinikini si lati ipilẹsẹ, Teofilu ọlọla jùlọ,

4. Ki iwọ ki o le mọ̀ ọtitọ ohun wọnni, ti a ti kọ́ ọ.

Ka pipe ipin Luk 1