Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kol 2:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ati ẹnyin, ẹniti o ti kú nitori ẹ̀ṣẹ nyin ati aikọla ara nyin, mo ni, ẹnyin li o si ti sọdi ãye pọ̀ pẹlu rẹ̀, o si ti dari gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin;

14. O si ti pa iwe majẹmu nì rẹ́, ti o lodi si wa, ti a kọ ninu ofin, eyiti o lodi si wa: on li o si ti mu kuro loju ọ̀na, o si kàn a mọ agbelebu;

15. O si ti já awọn ijọba ati agbara kuro li ara rẹ̀, o si ti dojuti wọn ni gbangba, o nyọ̀ ayọ̀ iṣẹgun lori wọn ninu rẹ̀.

16. Nitorina ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni mã ṣe idajọ nyin niti jijẹ, tabi niti mimu, tabi niti ọjọ ase, tabi oṣù titun, tabi ọjọ isimi:

17. Awọn ti iṣe ojiji ohun ti mbọ̀; ṣugbọn ti Kristi li ara.

18. Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni fi adabọwọ irẹlẹ ati bibọ awọn angẹli lọ́ ere nyin gbà lọwọ nyin, ẹniti nduro lori nkan wọnni ti o ti ri, ti o nti ipa ero rẹ̀ niti ara ṣeféfe asan,

19. Ti kò si di Ori nì mu ṣinṣin, lati ọdọ ẹniti a nti ipa orike ati iṣan pese fun gbogbo ara, ti a si nso o ṣọkan pọ, ti o si ndagba nipa ibisi Ọlọrun.

20. Bi ẹnyin ba ti kú pẹlu Kristi kuro ninu ipilẹṣẹ aiye, ẽhatiṣe ti ẹnyin ntẹriba fun ofin bi ẹnipe ẹnyin wà ninu aiye,

21. Maṣe fọwọkàn, maṣe tọ́wò, maṣe fọwọbà,

22. (Gbogbo eyiti yio ti ipa lilo run), gẹgẹ bi ofin ati ẹkọ́ enia?

23. Awọn nkan ti o ni afarawe ọgbọ́n nitõtọ, ni adabọwọ ìsin, ati irẹlẹ, ati ìpọn-ara-loju, ṣugbọn ti kò ni ere kan ninu fun ifẹkufẹ ara.

Ka pipe ipin Kol 2