Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 9:7-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. O si wi fun u pe, Lọ, wẹ̀ ninu adagun Siloamu, (itumọ̀ eyi ti ijẹ Ránlọ.) Nitorina o gbà ọ̀na rẹ̀ lọ, o wẹ̀, o si de, o nriran.

8. Njẹ awọn aladugbo ati awọn ti o ri i nigba atijọ pe alagbe ni iṣe, wipe, Ẹniti o ti njoko ṣagbe kọ́ yi?

9. Awọn kan wipe, On ni: awọn ẹlomiran wipe, Bẹ̃kọ, o jọ ọ ni: ṣugbọn on wipe, Emi ni.

10. Nitorina ni nwọn wi fun u pe, Njẹ oju rẹ ti ṣe là?

11. O dahùn o si wi fun wọn pe, ọkunrin kan ti a npè ni Jesu li o ṣe amọ̀, o si fi kùn mi loju, o si wi fun mi pe, Lọ si adagun Siloamu, ki o si wẹ̀: emi si lọ, mo wẹ̀, mo si riran.

12. Nwọn si wi fun u pe, On na ha dà? O wipe, emi kò mọ̀.

13. Nwọn mu ẹniti oju rẹ̀ ti fọ́ ri wá sọdọ awọn Farisi.

14. Njẹ ọjọ isimi lọjọ na nigbati Jesu ṣe amọ̀ na, ti o si là a loju.

15. Nitorina awọn Farisi pẹlu tún bi i lẽre, bi o ti ṣe riran. O si wi fun wọn pe, O fi amọ̀ le oju mi, mo si wẹ̀ mo si riran.

16. Nitorina awọn kan ninu awọn Farisi wipe, ọkunrin yi kò ti ọdọ Ọlọrun wá, nitoriti kò pa ọjọ isimi mọ́. Awọn ẹlomiran wipe, ọkunrin ti iṣe ẹlẹṣẹ yio ha ti ṣe le ṣe irú iṣẹ àmi wọnyi? Iyapa si wà larin wọn.

17. Nitorina nwọn si tun wi fun afọju na pe, Kini iwọ wi nitori rẹ̀, nitoriti o là ọ loju? O si wipe, Woli ni iṣe.

18. Nitorina awọn Ju kò gbagbọ́ nitori rẹ̀ pe, oju rẹ̀ ti fọ́ ri, ati pe o si tún riran, titi nwọn fi pe awọn obi ẹniti a ti là loju.

19. Nwọn si bi wọn lẽre, wipe, Eyi li ọmọ nyin, ẹniti ẹnyin wipe, a bí i li afọju? ẽhaṣe ti o riran nisisiyi?

20. Awọn obi rẹ̀ da wọn lohùn wipe, Awa mọ̀ pe ọmọ wa li eyi, ati pe a bí i li afọju:

21. Ṣugbọn bi o ti ṣe nriran nisisiyi awa kò mọ̀; tabi ẹniti o la a loju, awa kò mọ̀: ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre: yio wi fun ara rẹ̀.

22. Nkan wọnyi li awọn obi rẹ̀ sọ, nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn Ju: nitori awọn Ju ti fi ohùn ṣọkan pe, bi ẹnikan ba jẹwọ pe, Kristi ni iṣe, nwọn ó yọ ọ kuro ninu sinagogu.

23. Nitori eyi li awọn obi rẹ̀ fi wipe, Ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre.

Ka pipe ipin Joh 9