Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 7:44-53 Yorùbá Bibeli (YCE)

44. Awọn miran ninu wọn si fé lati mu u; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o gbé ọwọ́ le e.

45. Nitorina awọn onṣẹ pada tọ̀ awọn olori alufa ati awọn Farisi wá; nwọn si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi mu u wá?

46. Awọn onṣẹ dahùn wipe, Kò si ẹniti o ti isọ̀rọ bi ọkunrin yi ri.

47. Nitorina awọn Farisi da wọn lohùn wipe, A ha tàn ẹnyin jẹ pẹlu bi?

48. O ha si ẹnikan ninu awọn ijoye, tabi awọn Farisi ti o gbà a gbọ́?

49. Ṣugbọn ijọ enia yi, ti kò mọ̀ ofin, di ẹni ifibu.

50. Nikodemu si wi fun wọn pe, (ẹniti o tọ̀ Jesu wá loru, o jẹ ọkan ninu wọn),

51. Ofin wa nṣe idajọ enia ki o to gbọ ti ẹnu rẹ̀, ati ki o to mọ̀ ohun ti o ṣe bi?

52. Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Iwọ pẹlu nṣe ara Galili ndan? Wá kiri, ki o si wò: nitori kò si woli kan ti o ti Galili dide.

53. Nwọn si lọ olukuluku si ile rẹ̀.

Ka pipe ipin Joh 7