Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 4:19-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Obinrin na wi fun u pe, Ọgbẹni, mo woye pe, woli ni iwọ iṣe.

20. Awọn baba wa sìn lori òke yi; ẹnyin si wipe, Jerusalemu ni ibi ti o yẹ ti a ba ma sìn.

21. Jesu wi fun u pe, Gbà mi gbọ́, obinrin yi, wakati na mbọ̀, nigbati kì yio ṣe lori òke yi, tabi Jerusalemu, li ẹnyin o ma sìn Baba.

22. Ẹnyin nsìn ohun ti ẹnyin kò mọ̀: awa nsìn ohun ti awa mọ̀: nitori igbala ti ọdọ awọn Ju wá.

23. Ṣugbọn wakati mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn olusin tõtọ yio ma sìn Baba li ẹmí ati li otitọ: nitori irú wọn ni Baba nwá ki o ma sìn on.

24. Ẹmí li Ọlọrun: awọn ẹniti nsìn i ko le ṣe alaisìn i li ẹmí ati li otitọ.

25. Obinrin na wi fun u pe, mo mọ̀ pe Messia mbọ̀ wá, ti a npè ni Kristi: nigbati on ba de, yio sọ ohun gbogbo fun wa.

26. Jesu wi fun u pe, Emi ẹniti mba ọ sọ̀rọ yi li on.

27. Lori eyi li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ de, ẹnu si yà wọn, pe o mba obinrin sọ̀rọ: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o wipe, Kini iwọ nwá? tabi, Ẽṣe ti iwọ fi mba a sọ̀rọ?

28. Nigbana li obinrin na fi ladugbo rẹ̀ silẹ, o si mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n lọ si ilu, o si wi fun awọn enia pe,

29. Ẹ wá wò ọkunrin kan, ẹniti o sọ ohun gbogbo ti mo ti ṣe ri fun mi: eyi ha le jẹ Kristi na?

30. Nigbana ni nwọn ti ilu jade, nwọn si tọ̀ ọ wá.

31. Lãrin eyi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nrọ̀ ọ, wipe, Rabbi, jẹun.

32. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, emi li onjẹ lati jẹ, ti ẹnyin kò mọ̀.

33. Nitorina li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mbi ara wọn lère wipe, Ẹnikan mú onjẹ fun u wá lati jẹ bi?

34. Jesu wi fun wọn pe, Onjẹ mi ni lati ṣe ifẹ ẹniti o rán mi, ati lati pari iṣẹ rẹ̀.

35. Ẹnyin kò ha nwipe, O kù oṣù mẹrin, ikorè yio si de? wo o, mo wi fun nyin, Ẹ gbé oju nyin soke, ki ẹ si wó oko; nitoriti nwọn ti funfun fun ikore na.

36. Ẹniti nkorè ngba owo ọ̀ya, o si nkó eso jọ si ìye ainipẹkun: ki ẹniti o nfunrugbin ati ẹniti nkore le jọ mã yọ̀ pọ̀.

37. Nitori ninu eyi ni ọ̀rọ na fi jẹ otitọ: Ẹnikan li o fọnrugbin, ẹlomiran li o si nkòre jọ.

38. Mo rán nyin lọ ikore ohun ti ẹ kò ṣiṣẹ le lori: awọn ẹlomiran ti ṣiṣẹ, ẹnyin si wọ̀ inu iṣẹ wọn lọ.

Ka pipe ipin Joh 4