Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 17:11-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Emi kò si si li aiye mọ́, awọn wọnyi si mbẹ li aiye, emi si mbọ̀ wá sọdọ rẹ. Baba mimọ́, pa awọn ti o ti fifun mi mọ́, li orukọ rẹ, ki nwọn ki o le jẹ ọ̀kan, ani gẹgẹ bi awa.

12. Nigbati mo wà pẹlu wọn li aiye, mo pa wọn mọ li orukọ rẹ: awọn ti iwọ fifun mi, ni mo ti pamọ́, ẹnikan ninu wọn kò si ṣègbe bikoṣe ọmọ egbé; ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ.

13. Ṣugbọn nisisiyi emi si mbọ̀ wá sọdọ rẹ, nkan wọnyi ni mo si nsọ li aiye, ki nwọn ki o le ni ayọ̀ mi ni kikun ninu awọn tikarawọn.

14. Emi ti fi ọ̀rọ rẹ fun wọn; aiye si ti korira wọn, nitoriti nwọn kì iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi kì iti iṣe ti aiye.

15. Emi ko gbadura pe, ki iwọ ki o mu wọn kuro li aiye, ṣugbọn ki iwọ ki o pa wọn mọ́ kuro ninu ibi.

16. Nwọn kì iṣe ti aiye, gẹgẹ bi emi kì ti iṣe ti aiye.

17. Sọ wọn di mimọ́ ninu otitọ: otitọ li ọ̀rọ rẹ.

18. Gẹgẹ bi iwọ ti rán mi wá si aiye, bẹ̃ li emi si rán wọn si aiye pẹlu.

19. Emi si yà ara mi si mimọ́ nitori wọn, ki a le sọ awọn tikarawọn pẹlu di mimọ́ ninu otitọ.

Ka pipe ipin Joh 17