Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 14:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru: ẹ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹ gbà mi gbọ́ pẹlu.

2. Ninu ile Baba mi ọ̀pọlọpọ ibugbe li o wà: ibamáṣe bẹ̃, emi iba ti sọ fun nyin. Nitori emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin.

3. Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu.

4. Ẹnyin si mọ̀ ibi ti emi gbé nlọ, ẹ si mọ̀ ọ̀na na.

5. Tomasi wi fun u pe, Oluwa, a kò mọ̀ ibiti o gbe nlọ; a o ha ti ṣe mọ̀ ọ̀na na?

6. Jesu wi fun u pe, Emi li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi.

7. Ibaṣepe ẹnyin ti mọ̀ mi, ẹnyin iba ti mọ̀ Baba mi pẹlu: lati isisiyi lọ ẹnyin mọ̀ ọ, ẹ si ti ri i.

8. Filippi wi fun u pe, Oluwa, fi Baba na hàn wa, o si to fun wa.

9. Jesu wi fun u pe, Bi akokò ti mo ba nyin gbé ti pẹ to yi, iwọ kò si ti imọ̀ mi sibẹ̀ Filippi? ẹniti o ba ti ri mi, o ti ri Baba; iwọ ha ti ṣe wipe, Fi Baba hàn wa?

10. Iwọ kò ha gbagbọ́ pe, Emi wà ninu Baba, ati pe Baba wà ninu mi? ọ̀rọ ti emi nsọ fun nyin, emi kò da a sọ; ṣugbọn Baba ti ngbé inu mi, on ni nṣe iṣẹ rẹ̀.

11. Ẹ gbà mi gbọ́ pe, emi wà ninu Baba, Baba si wà ninu mi: bikoṣe bẹ̃, ẹ gbà mi gbọ́ nitori awọn iṣẹ na pãpã.

Ka pipe ipin Joh 14