Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 13:17-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Bi ẹnyin ba mọ̀ nkan wọnyi, alabukun-fun ni nyin, bi ẹnyin ba nṣe wọn.

18. Kì iṣe ti gbogbo nyin ni mo nsọ: emi mọ̀ awọn ti mo yàn: ṣugbọn ki iwe-mimọ́ ki o le ṣẹ, Ẹniti mba mi jẹun pọ̀ si gbé gigĩsẹ rẹ̀ si mi.

19. Lati isisiyi lọ mo sọ fun nyin ki o to de, pe nigbati o ba de, ki ẹnyin ki o le gbagbọ́ pe emi ni.

20. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà ẹnikẹni ti mo rán, o gbà mi; ẹniti o ba si gbà mi o gbà ẹniti o rán mi.

21. Nigbati Jesu ti wi nkan wọnyi tan, ọkàn rẹ̀ daru ninu rẹ̀, o si jẹri, o si wipe, Lõtọ lõtọ ni mo wi fun nyin pe, ọkan ninu nyin yio fi mi hàn.

22. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nwò ara wọn loju, nwọn nṣiye-meji ti ẹniti o wi.

23. Njẹ ẹnikan rọ̀gún si àiya Jesu, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ẹniti Jesu fẹràn.

24. Nitorina ni Simoni Peteru ṣapẹrẹ si i, o si wi fun u pe, Wi fun wa ti ẹniti o nsọ.

25. Ẹniti o nrọ̀gún li àiya Jesu wi fun u pe, Oluwa, tani iṣe?

26. Nitorina Jesu dahùn pe, On na ni, ẹniti mo ba fi òkele fun nigbati mo ba fi run. Nigbati o si fi i run tan, o fifun Judasi Iskariotu ọmọ Simoni.

27. Lẹhin òkele na ni Satani wọ̀ inu rẹ̀ lọ. Nitorina Jesu wi fun u pe, Ohun ti iwọ nṣe nì, yara ṣe e kánkan.

28. Kò si si ẹnikan nibi tabili ti o mọ̀ idi ohun ti o ṣe sọ eyi fun u.

29. Nitori awọn miran ninu wọn rò pe, nitori Judasi li o ni àpo, ni Jesu fi wi fun u pe, Rà nkan wọnni ti a kò le ṣe alaini fun ajọ na; tabi ki o le fi nkan fun awọn talakà.

30. Nigbati o si ti gbà òkele na tan, o jade lojukanna: oru si ni.

31. Nitorina nigbati o jade lọ tan, Jesu wipe, Nisisiyi li a yìn Ọmọ-enia logo, a si yìn Ọlọrun logo ninu rẹ̀.

Ka pipe ipin Joh 13