Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joh 10:32-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Jesu da wọn lohùn pe, Ọpọlọpọ iṣẹ rere ni mo fi hàn nyin lati ọdọ Baba mi wá; nitori ewo ninu iṣẹ wọnni li ẹnyin ṣe sọ mi li okuta?

33. Awọn Ju si da a lohùn, wipe, Awa kò sọ ọ li okuta nitori iṣẹ rere, ṣugbọn nitori ọrọ-odi: ati nitori iwọ ti iṣe enia nfi ara rẹ ṣe Ọlọrun.

34. Jesu da wọn lohùn pe, A kò ha ti kọ ọ ninu ofin nyin pe, Mo ti wipe, ọlọrun li ẹnyin iṣe?

35. Bi o ba pè wọn li ọlọrun, awọn ẹniti a fi ọ̀rọ Ọlọrun fun, a kò si le ba iwe-mimọ́ jẹ,

36. Ẹnyin ha nwi niti ẹniti Baba yà si mimọ́, ti o si rán si aiye pe, Iwọ nsọrọ-odi, nitoriti mo wipe Ọmọ Ọlọrun ni mi?

37. Bi emi kò ba ṣe iṣẹ Baba mi, ẹ máṣe gbà mi gbọ́.

38. Ṣugbọn bi emi ba ṣe wọn, bi ẹnyin kò tilẹ gbà mi gbọ́, ẹ gbà iṣẹ na gbọ́: ki ẹnyin ki o le mọ̀, ki o si le ye nyin pe, Baba wà ninu mi, emi si wà ninu rẹ̀.

39. Nwọn si tun nwá ọ̀na lati mu u: o si bọ́ lọwọ wọn.

40. O si tún kọja lọ si apakeji Jordani si ibiti Johanu ti kọ́ mbaptisi; nibẹ̀ li o si joko.

41. Awọn enia pipọ si wá sọdọ rẹ̀, nwọn si wipe, Johanu ko ṣe iṣẹ àmi kan: ṣugbọn otitọ li ohun gbogbo ti Johanu sọ nipa ti ọkunrin yi.

Ka pipe ipin Joh 10