Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jak 3:8-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ṣugbọn ahọn li ẹnikẹni kò le tù loju; ohun buburu alaigbọran ni, o kún fun oró iku ti ipa-ni.

9. On li awa fi nyìn Oluwa ati Baba, on li a si fi mbú enia, ti a dá li aworan Ọlọrun.

10. Lati ẹnu kanna ni iyìn ati ẽbú ti njade. Ẹnyin ará mi, nkan wọnyi kò yẹ ki o ri bẹ̃.

11. Orisun a ha mã sun omi tutù ati omiró jade lati ojusun kanna wá bi?

12. Ẹnyin ará mi, igi ọpọtọ ha le so eso olifi bi? tabi ajara le so eso ọpọtọ? bẹ̃li orisun kan kò le sun omiró ati omi tutù.

13. Tali o gbọ́n ti o si ni imọ̀ ninu nyin? ẹ jẹ ki o fi iṣẹ rẹ̀ hàn nipa ìwa rere, nipa ìwa tutù ti ọgbọn.

14. Ṣugbọn bi ẹnyin ba ni owú kikorò ati ìja li ọkàn nyin, ẹ máṣe ṣeféfe, ẹ má si ṣeke si otitọ.

15. Ọgbọ́n yi ki iṣe eyiti o ti oke sọkalẹ wá, ṣugbọn ti aiye ni, ti ara ni, ti ẹmí èṣu ni.

16. Nitori ibiti owú on ìja bá gbé wà, nibẹ̀ ni rudurudu ati iṣẹ buburu gbogbo wà.

17. Ṣugbọn ọgbọ́n ti o ti oke wá, a kọ́ mọ́, a si ni alafia, a ni ipamọra, kì isí iṣoro lati bẹ̀, a kún fun ãnu ati fun eso rere, li aisi ègbè, ati laisi agabagebe.

18. Eso ododo li a ngbìn li alafia fun awọn ti nṣiṣẹ alafia.

Ka pipe ipin Jak 3