Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jak 2:11-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nitori ẹniti o wipe, Máṣe ṣe panṣaga, on li o si wipe, Máṣe pania. Njẹ bi iwọ kò ṣe panṣaga, ṣugbọn ti iwọ pania, iwọ di arufin.

12. Ẹ mã sọrọ bẹ̃, ẹ si mã huwa bẹ̃, bi awọn ti a o fi ofin omnira dá li ẹjọ.

13. Nitori ẹniti kò ṣãnu, li a o ṣe idajọ fun laisi ãnu; ãnu nṣogo lori idajọ.

14. Ere kili o jẹ, ará mi, bi ẹnikan wipe on ni igbagbọ́, ṣugbọn ti kò ni iṣẹ? igbagbọ́ nì le gbà a là bi?

15. Bi arakunrin tabi arabinrin kan ba wà ni ìhoho, ti o si ṣe aili onjẹ õjọ,

16. Ti ẹnikan ninu nyin si wi fun wọn pe, Ẹ mã lọ li alafia, ki ara nyin ki o maṣe tutu, ki ẹ si yó; ṣugbọn ẹ kò fi nkan wọnni ti ara nfẹ fun wọn; ère kili o jẹ?

17. Bẹ̃ si ni igbagbọ́, bi kò ba ni iṣẹ, o kú ninu ara.

18. Ṣugbọn ẹnikan le wipe, Iwọ ni igbagbọ́, emi si ni iṣẹ: fi igbagbọ́ rẹ hàn mi li aisi iṣẹ, emi o si fi igbagbọ́ mi hàn ọ nipa iṣẹ mi.

19. Iwọ gbagbọ́ pe Ọlọrun kan ni mbẹ; o dara: awọn ẹmí èṣu pẹlu gbagbọ́, nwọn si warìri.

20. Ṣugbọn, iwọ alaimoye enia, iwọ ha fẹ mọ̀ pe, igbagbọ́ li aisi iṣẹ asan ni?

21. Kì ha iṣe nipa iṣẹ li a dá Abrahamu baba wa lare, nigbati o fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rubọ lori pẹpẹ?

22. Iwọ ri pe igbagbọ́ bá iṣẹ rẹ̀ rìn, ati pe nipa iṣẹ li a sọ igbagbọ́ di pipé.

23. Iwe-mimọ́ si ṣẹ ti o wipe, Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u: a si pè e li ọ̀rẹ́ Ọlọrun.

Ka pipe ipin Jak 2