Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

3. Joh 1:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ALÀGBA si Gaiu olufẹ, ẹniti mo fẹ ninu otitọ.

2. Olufẹ, emi ngbadura pe ninu ohun gbogbo ki o le mã dara fun ọ, ki o si mã wà ni ilera, ani bi o ti dara fun ọkàn rẹ.

3. Nitori mo yọ̀ gidigidi, nigbati awọn arakunrin de ti nwọn si jẹri si otitọ rẹ, ani bi iwọ ti nrìn ninu otitọ.

4. Emi kò ni ayọ̀ ti o pọjù eyi lọ, ki emi ki o mã gbọ́ pe, awọn ọmọ mi nrìn ninu otitọ.

5. Olufẹ, iwọ nṣe iṣẹ igbagbọ li ohunkohun ti o bá nṣe fun awọn ti iṣe ará ati fun awọn alejò;

6. Ti nwọn jẹri ifẹ rẹ niwaju ijọ: bi ìwọ bá npese fun wọn li ọna ajo wọn bi o ti yẹ nipa ti Ọlọrun, iwọ o ṣe ohun ti o dara.

7. Nitoripe nitori orukọ rẹ̀ ni nwọn ṣe jade lọ, li aigbà ohunkohun lọwọ awọn Keferi.

8. Njẹ o yẹ ki awa ki o gbà irú awọn wọnni, ki awa ki o le jẹ́ alabaṣiṣẹpọ pẹlu otitọ.

Ka pipe ipin 3. Joh 1