Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Tim 4:5-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ṣugbọn mã ṣe pẹlẹ ninu ohun gbogbo, mã farada ipọnju, ṣe iṣẹ efangelisti, ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laṣepe.

6. Nitori a nfi mi rubọ nisisiyi, atilọ mi si sunmọ etile.

7. Emi ti jà ìja rere, emi ti pari ire-ije mi, emi ti pa igbagbọ́ mọ́:

8. Lati isisiyi lọ a fi ade ododo lelẹ fun mi, ti Oluwa, onidajọ ododo, yio fifun mi li ọjọ na, kì si iṣe kìki emi nikan, ṣugbọn pẹlu fun gbogbo awọn ti o ti fẹ ifarahàn rẹ̀.

9. Sa ipa rẹ lati tete tọ̀ mi wá.

10. Nitori Dema ti kọ̀ mi silẹ, nitori o nfẹ aiye isisiyi, o si lọ si Tessalonika; Kreskeni si Galatia, Titu si Dalmatia.

11. Luku nikan li o wà pẹlu mi. Mu Marku wá pẹlu rẹ: nitori o wulo fun mi fun iṣẹ iranṣẹ.

12. Mo rán Tikiku ni iṣẹ lọ si Efesu.

13. Aṣọ otutu ti mo fi silẹ ni Troa lọdọ Karpu, nigbati iwọ ba mbọ̀ mu u wá, ati iwe wọnni, pẹlupẹlu iwe-awọ wọnni.

14. Aleksanderu alagbẹdẹ bàba ṣe mi ni ibi pupọ̀: Oluwa yio san a fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀:

15. Lọdọ ẹniti ki iwọ ki o mã ṣọra pẹlu; nitoriti o kọ oju ija si iwasu wa pupọ̀.

16. Li àtetekọ jẹ ẹjọ mi, kò si ẹniti o bá mi gba ẹjọ ro, ṣugbọn gbogbo enia li o kọ̀ mi silẹ: adura mi ni ki a máṣe kà a si wọn li ọrùn.

17. Ṣugbọn Oluwa gbà ẹjọ mi ro, o si fun mi lagbara; pe nipasẹ mi ki a le wãsu na ni awàjálẹ̀, ati pe ki gbogbo awọn Keferi ki o le gbọ́: a si gbà mi kuro li ẹnu kiniun nì.

18. Oluwa yio yọ mi kuro ninu iṣẹ buburu gbogbo, yio si gbé mi de inu ijọba rẹ̀ ọrun: ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin.

19. Kí Priskilla ati Akuila, ati ile Onesiforu.

Ka pipe ipin 2. Tim 4