Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Tim 2:2-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ati ohun wọnni ti iwọ ti gbọ́ lọdọ mi lati ọwọ ọ̀pọlọpọ ẹlẹri, awọn na ni ki iwọ fi le awọn olõtọ enia lọwọ, awọn ti yio le mã kọ́ awọn ẹlomiran pẹlu.

3. Ṣe alabapin pẹlu mi ninu ipọnju, bi ọmọ-ogun rere Jesu Kristi.

4. Kò si ẹniti njàgun ti ifi ohun aiye yi dí ara rẹ̀ lọwọ, ki o le mu inu ẹniti o yàn a li ọmọ-ogun dùn.

5. Bi ẹnikẹni ba si njà, a kì dé e li ade, bikoṣepe o ba jà li aiṣe erú.

6. Àgbẹ ti o nṣe lãlã li o ni lati kọ́ mu ninu eso wọnni.

7. Gbà ohun ti emi nsọ rò; nitori Oluwa yio fun ọ li òye ninu ohun gbogbo.

8. Ranti Jesu Kristi, ti o jinde kuro ninu okú, lati inu irú-ọmọ Dafidi, gẹgẹ bi ihinrere mi,

9. Ninu eyiti emi nri ipọnju titi dé inu ìde bi arufin; ṣugbọn a kò dè ọ̀rọ Ọlọrun.

10. Nitorina mo nfarada ohun gbogbo nitori ti awọn ayanfẹ, ki awọn na pẹlu le ni igbala ti mbẹ ninu Kristi Jesu pẹlu ogo ainipẹkun.

11. Otitọ li ọrọ na: Nitoripe bi awa ba bá a kú, awa ó si bá a yè:

12. Bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba: bi awa ba sẹ́ ẹ, on na yio si sẹ́ wa.

13. Bi awa kò ba gbagbọ́, on duro li olõtọ: nitori on kò le sẹ́ ara rẹ̀.

14. Nkan wọnyi ni ki o mã rán wọn leti, mã kìlọ fun wọn niwaju Oluwa pe, ki nwọn ki o máṣe jijà ọ̀rọ ti kò lere, fun iparun awọn ti ngbọ.

15. Ṣãpọn lati fi ara rẹ hàn niwaju Ọlọrun li ẹniti o yege, aṣiṣẹ́ ti kò ni lati tiju, ti o npín ọ̀rọ otitọ bi o ti yẹ.

Ka pipe ipin 2. Tim 2