Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Tes 2:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ṢUGBỌN awa mbẹ̀ nyin, ará, nitori ti wíwa Jesu Kristi Oluwa wa, ati ti ipejọ wa sọdọ rẹ̀,

2. Ki ọkàn nyin ki o máṣe tete mì, tabi ki ẹ máṣe jaiya, yala nipa ẹmí, tabi nipa ọ̀rọ, tabi nipa iwe bi lati ọdọ wa wá, bi ẹnipe ọjọ Oluwa de.

3. Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni tàn nyin jẹ lọnakọna; nitoripe ọjọ na ki yio de, bikoṣepe ìyapa nì ba kọ́ de, ki a si fi ẹni ẹ̀ṣẹ nì hàn, ti iṣe ọmọ ègbé;

4. Ẹniti nṣòdì, ti o si ngbé ara rẹ̀ ga si gbogbo ohun ti a npè li Ọlọrun, tabi ti a nsin; tobẹ ti o joko ni tẹmpili Ọlọrun, ti o nfi ara rẹ̀ hàn pe Ọlọrun li on.

5. Ẹnyin kò ranti pe, nigbati mo wà lọdọ nyin, mo nsọ̀ nkan wọnyi fun nyin?

6. Ati nisisiyi ẹnyin mọ ohun ti o nṣe idena, ki a le ba fi i hàn li akokò rẹ̀.

7. Nitoripe ohun ijinlẹ ẹ̀ṣẹ ti nṣiṣẹ ná: kìki pe ẹnikan wà ti nṣe idena nisisiyi, titi a ó fi mu u ti ọ̀na kuro.

8. Nigbana li a ó si fi ẹ̀ṣẹ nì hàn, ẹniti Oluwa yio fi ẽmi ẹnu rẹ̀ pa, ti yio si fi ifihan wíwa rẹ̀ sọ di asan:

Ka pipe ipin 2. Tes 2