Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Pet 2:16-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Ṣugbọn a ba a wi nitori irekọja rẹ̀: odi kẹtẹkẹtẹ fi ohùn enia sọ̀rọ, o si fi opin si were wolĩ na.

17. Awọn wọnyi ni kanga ti kò li omi, ikũku ti ẹfũfu ngbá kiri; awọn ẹniti a pa òkunkun biribiri mọ́ de tití lai.

18. Nitori igbati nwọn ba nsọ̀rọ ihalẹ asan, ninu ifẹkufẹ ara, nipa wọbia, nwọn a mã tan awọn ti nwọn fẹrẹ má ti ibọ tan kuro lọwọ ti nwọn wà ninu iṣina.

19. Nwọn a mã ṣe ileri omnira fun wọn, nigbati awọn pãpã jẹ ẹrú idibajẹ́: nitori ẹniti o ba ṣẹgun ẹni, on na ni isi sọ ni di ẹrú.

20. Nitori lẹhin ti nwọn ba ti yọ tan kuro ninu ẽri aiye, nipa mimọ̀ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi, bi nwọn ba si tun fi ara kó o, ti a si ṣẹgun wọn, igbẹhin wọn a buru jù ti iṣaju lọ.

21. Nitori ìba san fun wọn, ki nwọn ki o má mọ̀ ọ̀na ododo, jù lẹhin ti nwọn mọ̀ ọ tan, ki nwọn ki o yipada kuro ninu ofin mimọ́ ti a fifun wọn.

22. Owe otitọ nì ṣẹ si wọn lara, Ajá tún pada si ẽbì ara rẹ̀; ati ẹlẹdẹ ti a ti wẹ̀ mọ́ sinu àfọ ninu ẹrẹ̀.

Ka pipe ipin 2. Pet 2