Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kor 8:17-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Nitori on gbà ọ̀rọ iyanju nitõtọ; ṣugbọn bi o ti ni itara pipọ, on tikararẹ̀ tọ̀ nyin wá fun ara rẹ̀.

18. Awa ti rán arakunrin na pẹlu rẹ̀, iyìn ẹniti o wà ninu ihinrere yiká gbogbo ijọ.

19. Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn ẹniti a ti yàn pẹlu lati ọdọ ijọ wá lati mã bá wa rìn kiri ninu ọran ore-ọfẹ yi, ti awa nṣe iranṣẹ rẹ̀ fun ogo Oluwa, ati imura-tẹlẹ wa.

20. Awa nyẹra fun eyi, ki ẹnikẹni má bã ri wi si wa nitori ọ̀pọ yi ti awa pin.

21. Awa ngbero ohun rere, kì iṣe niwaju Oluwa nikan, ṣugbọn niwaju enia pẹlu.

22. Awa si ti rán arakunrin wa pẹlu wọn, ẹniti awa ri daju nigba pipọ pe o ni itara ninu ohun pipọ, ṣugbọn nisisiyi ni itara rẹ̀ tubọ pọ si i nipa igbẹkẹle nla ti o ni si nyin.

23. Bi ẹnikẹni ba mbère ẹniti Titu iṣe, ẹlẹgbẹ ati olubaṣiṣẹ mi ni nitori nyin: tabi awọn arakunrin wa li ẹnikẹni mbère ni, iranṣẹ ijọ ni nwọn iṣe, ati ogo Kristi.

24. Nitorina ẹ fi ẹri ifẹ nyin hàn wọn niwaju ijọ, ati iṣogo wa nitori nyin.

Ka pipe ipin 2. Kor 8