Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kor 5:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NITORI awa mọ̀ pe, bi ile agọ́ wa ti aiye bá wó, awa ni ile kan lati ọdọ Ọlọrun, ile ti a kò fi ọwọ́ kọ́, ti aiyeraiye ninu awọn ọrun.

2. Nitori nitõtọ awa nkerora ninu eyi, awa si nfẹ gidigidi lati fi ile wa lati ọrun wá wọ̀ wa:

3. Bi o ba ṣepe a ti wọ̀ wa li aṣọ, a kì yio bá wa ni ìhoho.

4. Nitori awa ti mbẹ ninu agọ́ yi nkerora nitõtọ, ẹrù npa wa: kì iṣe nitori ti awa nfẹ ijẹ alaiwọ̀ṣọ, ṣugbọn ki a le wọ̀ wa li aṣọ, ki iyè ki o le gbé ara kiku mì.

5. Njẹ ẹniti o ṣe wa fun nkan yi ni Ọlọrun, ẹniti o si ti fi akọso Ẹmí fun wa pẹlu.

6. Nitorina awa ni igboiya nigbagbogbo, awa si mọ̀ pe, nigbati awa mbẹ ni ile ninu ara, awa kò si lọdọ Oluwa:

7. (Nitoripe nipa igbagbọ́ li awa nrìn, kì iṣe nipa riri:)

8. Mo ni, awa ni igboiya, awa si nfẹ ki a kuku ti inu ara kuro, ki a si le wà ni ile lọdọ Oluwa.

Ka pipe ipin 2. Kor 5