1. NITORINA bi awa ti ni iṣẹ-iranṣẹ yi, gẹgẹ bi a ti ri ãnu gbà, ãrẹ̀ kò mu wa;
2. Ṣugbọn awa ti kọ̀ gbogbo ohun ìkọkọ ti o ni itiju silẹ, awa kò rìn li ẹ̀tan, bẹ̃li awa kò fi ọwọ́ ẹ̀tan mu ọ̀rọ Ọlọrun; ṣugbọn nipa fifi otitọ hàn, awa nfi ara wa le ẹri-ọkàn olukuluku enia lọwọ niwaju Ọlọrun.
3. Ṣugbọn bi ihinrere wa ba si farasin, o farasin fun awọn ti o nù:
4. Ninu awọn ẹniti ọlọrun aiye yi ti sọ ọkàn awọn ti kò gbagbọ́ di afọju, ki imọlẹ ihinrere Kristi ti o logo, ẹniti iṣe aworan Ọlọrun, ki o máṣe mọlẹ ninu wọn.
5. Nitori awa kò wãsu awa tikarawa, bikoṣe Kristi Jesu Oluwa; awa tikarawa si jẹ ẹrú nyin nitori Jesu.
6. Nitori Ọlọrun, ẹniti o wipe ki imọlẹ ki o mọlẹ lati inu òkunkun jade, on li o ti nmọlẹ li ọkàn wa, lati fun wa ni imọlẹ ìmọ ogo Ọlọrun li oju Jesu Kristi.