Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kor 2:7-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Kaka bẹ ẹ, ẹnyin iba kuku darijì i, ki ẹ si tù u ninu, lọnakọna ki ọpọlọpọ ibanujẹ má bã bò iru enia bẹ̃ mọlẹ.

8. Nitorina mo bẹ̀ nyin, ẹ fi ifẹ nyin han daju si oluwarẹ̀.

9. Nitori eyi na pẹlu ni mo ti kọwe, ki emi ki o le mọ̀ ẹri nyin, bi ẹnyin ba ṣe eletí ọmọ li ohun gbogbo.

10. Ṣugbọn ẹniti ẹnyin ba fi ohunkohun jì fun, emi fi jì pẹlu: nitori ohun ti emi pẹlu ba ti fi jì, bi mo ba ti fi ohunkohun jì, nitori tinyin ni mo ti fi ji niwaju Kristi.

11. Ki Satani má bã rẹ́ wa jẹ: nitori awa kò ṣe alaimọ̀ arekereke rẹ̀.

12. Ṣugbọn nigbati mo de Troa lati wãsu ihinrere Kristi, ti ilẹkun si ṣí silẹ fun mi lati ọdọ Oluwa wá,

13. Emi kò ni alafia li ọkàn mi, nitoriti emi ko ri Titu arakunrin mi: ṣugbọn nigbati mo ti dagbere fun wọn, mo rekọja lọ si Makedonia.

14. Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun, ẹniti nyọ̀ ayọ iṣẹgun lori wa nigbagbogbo ninu Kristi, ti o si nfi õrùn ìmọ rẹ̀ hàn nipa wa nibigbogbo.

15. Nitori õrun didùn Kristi li awa jẹ fun Ọlọrun, ninu awọn ti a ngbalà, ati ninu awọn ti o nṣegbé:

16. Fun awọn kan, awa jẹ õrun ikú si ikú, ati fun awọn miran õrun iyè. Tali o ha si to fun nkan wọnyi?

17. Nitori awa kò dabi awọn ọ̀pọlọpọ, ti mba ọ̀rọ Ọlọrun jẹ́: ṣugbọn bi nipa otitọ inu, ṣugbọn bi lati ọdọ Ọlọrun wá, niwaju Ọlọrun li awa nsọ̀rọ ninu Kristi.

Ka pipe ipin 2. Kor 2