Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kor 12:16-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Ṣugbọn o dara bẹ̃, ti emi kò dẹruba nyin: ṣugbọn bi ọlọgbọn, emi nfi ẹ̀rọ mu nyin.

17. Emi ha rẹ́ nyin jẹ nipa ẹnikẹni ninu awọn ti mo rán si nyin bi?

18. Mo bẹ̀ Titu, mo si rán arakunrin kan pẹlu rẹ̀; Titu ha rẹ́ nyin jẹ bi? nipa ẹmí kanna kọ́ awa rìn bi? ọ̀na kanna kọ́ awa tọ̀ bi?

19. Ẹnyin ha rò pe ni gbogbo akoko yi àwa nṣe àwíjàre niwaju nyin? awa nsọ̀rọ niwaju Ọlọrun ninu Kristi: ṣugbọn awa nṣe ohun gbogbo, olufẹ ọwọn, lati mu nyin duro.

20. Nitori ẹru mba mi pe, nigbati mo ba de, emi kì yio bá nyin gẹgẹ bi irú eyi ti mo fẹ, ati pe ẹnyin ó si ri mi gẹgẹ bi irú eyi ti ẹnyin kò fẹ: ki ija, owu-jijẹ, ibinu, ipinya, isọrọ-ẹni-lẹhin, ijirọsọ, igberaga, irukerudo, ki o má ba wà:

21. Ati nigbati mo ba si pada de, ki Ọlọrun mi má ba rẹ̀ mi silẹ loju nyin, ati ki emi ki o má bã sọkun nitori ọpọlọpọ awọn ti o ti ṣẹ̀ na, ti nwọn kò si ronupiwada ẹ̀ṣẹ ìwa-ẽri, ati ti àgbere, ati ti wọ̀bia ti nwọn ti dá.

Ka pipe ipin 2. Kor 12