Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kor 11:27-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Ninu lãlã ati irora, ninu iṣọra nigbakugba, ninu ebi ati orùngbẹ, ninu àwẹ nigbakugba, ninu otutù ati ìhoho.

28. Pẹlu nkan wọnni ti o wà lode, eyi ti nwọjọ tì mi li ojojumọ́, emi ko yé ṣe aniyan gbogbo ijọ.

29. Tani iṣe alailera, ti emi kò ṣe alailera? tabi tali a mu kọsẹ̀, ti ara mi kò gbina?

30. Bi emi kò le ṣaima ṣogo, emi o kuku mã ṣogo nipa awọn nkan ti iṣe ti ailera mi.

31. Ọlọrun ati Baba Oluwa wa Jesu Kristi, ẹniti iṣe olubukún julọ lailai, mọ̀ pe emi kò ṣeke.

32. Ni Damasku, bãlẹ ti o wà labẹ ọba Areta fi ẹgbẹ ogun ká ilu awọn ara Damasku mọ́, o nfẹ mi lati mu:

33. Ati loju ferese ninu agbọ̀n li a si ti sọ̀ mi kalẹ lẹhin odi, ti mo si bọ́ lọwọ rẹ̀.

Ka pipe ipin 2. Kor 11