Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kor 11:2-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Nitoripe emi njowú lori nyin niti owú ẹni ìwa-bi-Ọlọrun: nitoriti mo ti fi nyin fun ọkọ kan, ki emi ki o le mu nyin wá bi wundia ti o mọ́ sọdọ Kristi.

3. Ṣugbọn ẹru mba mi pe, li ohunkohun, gẹgẹ bi ejò ti tàn Efa jẹ nipasẹ arekereke rẹ̀, ki a maṣe mu ero-ọkàn nyin bajẹ kuro ninu inu kan ati iwa mimọ́ nyin si Kristi.

4. Nitori bi ẹniti mbọ̀ wá ba nwãsu Jesu miran, ti awa kò ti wasu rí, tabi bi ẹnyin ba gbà ẹmí miran, ti ẹnyin kò ti gbà ri, tabi ihinrere miran, ti ẹnyin kò ti tẹwọgbà, ẹnyin iba ṣe rere lati fi ara da a.

5. Nitori mo ṣiro rẹ pe emi kò rẹ̀hin li ohunkohun si awọn Aposteli gigagiga na.

6. Ṣugbọn bi mo tilẹ jẹ òpe li ọ̀rọ, ki iṣe ni ìmọ; ṣugbọn awa ti fihan dajudaju fun nyin lãrin gbogbo enia.

7. Tabi ẹ̀ṣẹ ni mo dá ti emi nrẹ̀ ara mi silẹ ki a le gbé nyin ga, nitoriti mo ti wasu ihinrere Ọlọrun fun nyin lọfẹ?

8. Emi ja ijọ miran li ole, mo ngbà owo ki emi ki o le sìn nyin.

9. Nigbati mo si wà pẹlu nyin, ti mo si ṣe alaini, emi kò jẹ́ ẹrù fun ẹnikẹni: nitoriti ohun ti mo ṣe alaini awọn ara ti o ti Makedonia wá fi kún u; ati ninu ohun gbogbo mo ti pa ara mi mọ́ ki emi maṣe jẹ ẹrù fun nyin, bẹ̃li emi ó si mã pa ara mi mọ́.

10. Bi otitọ Kristi ti mbẹ ninu mi, kò sí ẹniti o le da mi lẹkun iṣogo yi ni gbogbo ẹkùn Akaia.

11. Nitori kini? nitori emi kò fẹran nyin ni bi? Ọlọrun mọ̀.

12. Ṣugbọn ohun ti mo nṣe li emi ó si mã ṣe, ki emi ki o le mu igberaga kuro lọwọ awọn ti gberaga pe ninu ohun ti nwọn nṣogo, ki a le ri wọn gẹgẹ bi awa.

13. Nitori irú awọn enia bẹ̃ li awọn eke Aposteli, awọn ẹniti nṣiṣẹ ẹ̀tan, ti npa ara wọn dà di Aposteli Kristi.

14. Kì si iṣe ohun iyanu; nitori Satani tikararẹ̀ npa ara rẹ̀ dà di angẹli imọlẹ.

15. Nitorina kì iṣe ohun nla bi awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu ba pa ara wọn dà bi awọn iranṣẹ ododo; igbẹhin awọn ẹniti yio ri gẹgẹ bi iṣẹ wọn.

16. Mo si tún wipe, Ki ẹnikẹni ki o máṣe rò pe aṣiwère ni mi; ṣugbọn bi bẹ̃ ba ni, ẹ gbà mi bi aṣiwere, ki emi ki o le gbé ara mi ga diẹ.

Ka pipe ipin 2. Kor 11