Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kor 11:11-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nitori kini? nitori emi kò fẹran nyin ni bi? Ọlọrun mọ̀.

12. Ṣugbọn ohun ti mo nṣe li emi ó si mã ṣe, ki emi ki o le mu igberaga kuro lọwọ awọn ti gberaga pe ninu ohun ti nwọn nṣogo, ki a le ri wọn gẹgẹ bi awa.

13. Nitori irú awọn enia bẹ̃ li awọn eke Aposteli, awọn ẹniti nṣiṣẹ ẹ̀tan, ti npa ara wọn dà di Aposteli Kristi.

14. Kì si iṣe ohun iyanu; nitori Satani tikararẹ̀ npa ara rẹ̀ dà di angẹli imọlẹ.

15. Nitorina kì iṣe ohun nla bi awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu ba pa ara wọn dà bi awọn iranṣẹ ododo; igbẹhin awọn ẹniti yio ri gẹgẹ bi iṣẹ wọn.

16. Mo si tún wipe, Ki ẹnikẹni ki o máṣe rò pe aṣiwère ni mi; ṣugbọn bi bẹ̃ ba ni, ẹ gbà mi bi aṣiwere, ki emi ki o le gbé ara mi ga diẹ.

17. Ohun ti emi nsọ, emi kò sọ ọ nipa ti Oluwa, ṣugbọn bi aṣiwèrè ninu igbẹkẹle iṣogo yi.

18. Ọpọlọpọ li o sa nṣogo nipa ti ara, emi ó ṣogo pẹlu.

19. Nitori ẹnyin fi inu didùn gbà awọn aṣiwère, nigbati ẹnyin tikaranyin jẹ ọlọ́gbọn.

Ka pipe ipin 2. Kor 11