Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kor 1:6-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Ṣugbọn bi a ba si npọ́n wa loju ni, o jasi bi itunu ati igbala nyin, ti nṣiṣẹ ni ifàiyarán awọn iya kannã ti awa pẹlu njẹ: tabi bi a ba ntù wa ninu, o jasi fun itunu ati igbala nyin.

7. Ati ireti wa nipa tiyin duro ṣinṣin, awa si mọ̀ pe, bi ẹnyin ti jẹ alabapin ninu ìya, bẹ̃li ẹnyin jẹ ninu itunu na pẹlu.

8. Ará, awa kò sá fẹ ki ẹnyin ki o wà li aimọ̀ nipa wahalà wa, ti o dé bá wa ni Asia, niti pe a pọ́n wa loju gidigidi rekọja agbara wa, tobẹ̃ ti ireti kò tilẹ si fun ẹmi wa mọ́:

9. Ṣugbọn awa ni idahùn ikú ninu ara wa, ki awa ki o máṣe gbẹkẹle ara wa, bikoṣe Ọlọrun ti njí okú dide:

10. Ẹniti o ti gbà wa kuro ninu ikú ti o tobi tobẹ̃, ti o si ngbà wa: ẹniti awa gbẹkẹ wa le pe yio si mã gbà wa sibẹsibẹ;

11. Ẹnyin pẹlu nfi adura nyin ṣe iranlọwọ fun wa, pe nitori ẹ̀bun ti a fifun wa lati ọwọ ọ̀pọlọpọ enia, ki ọ̀pọlọpọ ki o le mã dupẹ nitori wa.

12. Nitori eyi ni iṣogo wa, ẹ̀rí-ọkàn wa, pe, ni iwa-mimọ́ ati ododo Ọlọrun, kì iṣe nipa ọgbọ́n ara, bikoṣe nipa ore-ọfẹ Ọlọrun, li awa nhuwa li aiye, ati si nyin li ọ̀pọlọpọ.

13. Nitoripe awa kò kọwe ohun miran si nyin jù eyi ti ẹnyin kà lọ, tabi ti ẹnyin ti gbà pẹlu: mo si gbẹkẹle pe ẹnyin ó gba a titi de opin;

14. Gẹgẹ bi ẹnyin si ti jẹwọ wa pẹlu li apakan pe, awa ni iṣogo nyin, gẹgẹ bi ẹnyin pẹlu ti jẹ iṣogo wa li ọjọ Jesu Oluwa.

15. Ati ninu igbẹkẹle yi ni mo ti ngbèro ati tọ̀ nyin wá niṣãjú, ki ẹnyin ki o le ni ayọ nigbakeji;

Ka pipe ipin 2. Kor 1