Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kor 1:13-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nitoripe awa kò kọwe ohun miran si nyin jù eyi ti ẹnyin kà lọ, tabi ti ẹnyin ti gbà pẹlu: mo si gbẹkẹle pe ẹnyin ó gba a titi de opin;

14. Gẹgẹ bi ẹnyin si ti jẹwọ wa pẹlu li apakan pe, awa ni iṣogo nyin, gẹgẹ bi ẹnyin pẹlu ti jẹ iṣogo wa li ọjọ Jesu Oluwa.

15. Ati ninu igbẹkẹle yi ni mo ti ngbèro ati tọ̀ nyin wá niṣãjú, ki ẹnyin ki o le ni ayọ nigbakeji;

16. Ati lati kọja lọdọ nyin lọ si Makedonia, ati lati tún wá sọdọ nyin lati Makedonia, ati lati mu mi lati ọdọ nyin lọ si Judea.

17. Nitorina nigbati emi ngbèro bẹ̃, emi ha ṣiyemeji bi? tabi ohun wọnni ti mo pinnu, mo ha pinnu wọn gẹgẹ bi ti ara bi, pe ki o jẹ bẹ̃ni bẹ̃ni, ati bẹ̃kọ, bẹ̃kọ lọdọ mi?

18. Ṣugbọn bi Ọlọrun ti jẹ olõtọ, ọ̀rọ wa fun nyin kì iṣe bẹ̃ni ati bẹ̃kọ.

19. Nitoripe Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun, ẹniti a ti wasu rẹ̀ larin nyin nipasẹ wa, ani nipasẹ emi ati Silfanu ati Timotiu, kì iṣe bẹ̃ni ati bẹ̃kọ, ṣugbọn ninu rẹ̀ ni bẹ̃ni.

20. Nitoripe bi o ti wu ki ileri Ọlọrun pọ̀ to, ninu rẹ̀ ni bẹ̃ni: ati ninu rẹ̀ pẹlu ni Amin, si ogo Ọlọrun nipasẹ wa.

21. Njẹ nisisiyi, ẹniti o fi ẹsẹ wa mulẹ pẹlu nyin ninu Kristi, ti o si fi àmi oróro yàn wa, ni Ọlọrun;

22. Ẹniti o si ti fi èdidi di wa pẹlu, ti o si ti fi akọso eso Ẹmí si wa li ọkàn.

23. Mo si pè Ọlọrun ṣe ẹlẹri li ọkàn mi pe, nitori lati dá nyin si li emi kò ṣe ti wá si Korinti.

24. Kì iṣe nitoriti awa tẹ́ gàbá lori igbagbọ́ nyin, ṣugbọn awa jẹ́ oluranlọwọ ayọ̀ nyin: nitori ẹnyin duro nipa igbagbọ́.

Ka pipe ipin 2. Kor 1