Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Joh 1:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EMI alàgba si ayanfẹ obinrin ọlọlá ati awọn ọmọ rẹ̀, awọn ti mo fẹ li otitọ; kì si iṣe emi nikan, ṣugbọn gbogbo awọn ti o mọ̀ otitọ pẹlu;

2. Nitori otitọ ti ngbé inu wa, yio si mã ba wa gbé titi.

3. Õre-ọfẹ, ãnu, ati alafia, yio wà pẹlu wa, lati ọdọ Ọlọrun Baba, ati lati ọdọ Jesu Kristi, Ọmọ Baba, ninu otitọ ati ninu ifẹ.

4. Mo yọ̀ gidigidi pe mo ti ri ninu awọn ọmọ rẹ ti nrin ninu otitọ, ani bi awa ti gbà ofin lati ọdọ Baba.

5. Njẹ nisisiyi mo bẹ̀ ọ, obinrin ọlọlá, kì iṣe bi ẹnipe emi nkọwe ofin titun kan si ọ, bikọse eyi ti awa ti ni li àtetekọṣe, pe ki awa ki o fẹràn ara wa.

Ka pipe ipin 2. Joh 1