Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 7:43-60 Yorùbá Bibeli (YCE)

43. Ẹnyin si tẹwọgbà agọ́ Moloku, ati irawọ oriṣa Remfani, aworan ti ẹnyin ṣe lati mã bọ wọn: emi ó si kó nyin lọ rekọja Babiloni.

44. Awọn baba wa ni agọ ẹri ni ijù, bi ẹniti o ba Mose sọrọ ti paṣẹ pe, ki o ṣe e gẹgẹ bi apẹrẹ ti o ti ri;

45. Ti awọn baba wa ti o tẹle wọn si mu ba Joṣua wá si ilẹ-ini awọn Keferi, ti Ọlọrun lé jade kuro niwaju awọn baba wa, titi di ọjọ Dafidi;

46. Ẹniti o ri ojurere niwaju Ọlọrun, ti o si tọrọ lati ri ibugbe fun Ọlọrun Jakọbu.

47. Ṣugbọn Solomoni kọ́ ile fun u.

48. Ṣugbọn Ọgá-ogo kì igbé ile ti a fi ọwọ kọ́; gẹgẹ bi woli ti wipe,

49. Ọrun ni itẹ́ mi, aiye si li apoti itisẹ mi: irú ile kili ẹnyin o kọ́ fun mi? li Oluwa wi; tabi ibo ni ibi isimi mi?

50. Ọwọ́ mi kọ́ ha ṣe gbogbo nkan wọnyi?

51. Ẹnyin ọlọrùn-lile ati alaikọla àiya on etí, nigba-gbogbo li ẹnyin ima dèna Ẹmí Mimọ́: gẹgẹ bi awọn baba nyin, bẹ̃li ẹnyin.

52. Tani ninu awọn woli ti awọn baba nyin kò ṣe inunibini si? nwọn si ti pa awọn ti o ti nsọ asọtẹlẹ ti wíwa Ẹni Olõtọ nì; ẹniti ẹnyin si ti di olufihàn ati olupa:

53. Ẹnyin ti o gbà ofin, gẹgẹ bi ilana awọn angẹli, ti ẹ kò si pa a mọ́.

54. Nigbati nwọn si gbọ́ nkan wọnyi, àiya wọn gbọgbẹ́ de inu, nwọn si pahin si i keke.

55. Ṣugbọn on kún fun Ẹmí Mimọ́, o tẹjumọ́ ọrun, o si ri ogo Ọlọrun, ati Jesu nduro li ọwọ́ ọtún Ọlọrun.

56. O si wipe, Wò o, mo ri ọrun ṣí silẹ, ati Ọmọ-enia nduro li ọwọ́ ọtún Ọlọrun.

57. Nigbana ni nwọn kigbe li ohùn rara, nwọn si dì eti wọn, nwọn si fi ọkàn kan rọ́ lù u,

58. Nwọn si wọ́ ọ sẹhin ode ilu, nwọn sọ ọ lí okuta: awọn ẹlẹri si fi aṣọ wọn lelẹ li ẹsẹ ọmọkunrin kan ti a npè ni Saulu.

59. Nwọn sọ Stefanu li okuta, o si nképe Oluwa wipe, Jesu Oluwa, gbà ẹmí mi.

60. O si kunlẹ, o kigbe li ohùn rara pe, Oluwa, má kà ẹ̀ṣẹ yi si wọn li ọrùn. Nigbati o si wi eyi, o sùn.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 7