Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 7:21-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nigbati nwọn si gbe e sọnù, ọmọbinrin Farao he e, o si tọ́ ọ dàgba li ọmọ ara rẹ̀.

22. A si kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ará Egipti, o si pọ̀ li ọ̀rọ ati ni iṣe.

23. Nigbati o si di ẹni iwọn ogoji ọdún, o sọ si i lọkan lati lọ ibẹ̀ awọn ọmọ Israeli ará rẹ̀ wò.

24. Nigbati o si ri ọkan ninu wọn ti a njẹ ni ìya, o gbejà rẹ̀, o gbẹsan ẹniti nwọn njẹ ni ìya, o si lu ara Egipti na pa:

25. O si ṣebi awọn ará on mọ̀ bi Ọlọrun yio ti ti ọwọ́ on gbà wọn: ṣugbọn nwọn kò mọ̀.

26. O si di ijọ keji o yọ si wọn bi nwọn ti njà, on iba si pari rẹ̀ fun wọn, o wipe, Alàgba, ará li ẹnyin; ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe ohun ti kò tọ́ si ara nyin?

27. Ṣugbọn ẹniti o finran si ẹnikeji rẹ̀ tì i kuro, o wipe, Tali o fi ọ jẹ olori ati onidajọ wa?

28. Iwọ nfẹ pa mi gẹgẹ bi o ti pa ará Egipti laná?

29. Mose si sá nitori ọ̀rọ yi, o si wa ṣe atipo ni ilẹ Midiani, nibiti o gbé bí ọmọ meji.

30. Nigbati ogoji ọdún si pé, angẹli Oluwa farahàn a ni ijù, li òke Sinai, ninu ọwọ́ iná ni igbẹ́.

31. Nigbati Mose si ri i, ẹnu yà a si iran na: nigbati o si sunmọ ọ lati wò o fín, ohùn Oluwa kọ si i,

32. Wipe, Emi li Ọlọrun awọn baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu. Mose si warìri, kò si daṣa lati wò o mọ́.

33. Oluwa si wi fun u pe, Tú bata rẹ kuro li ẹsẹ rẹ: nitori ibi ti iwọ gbé duro nì ilẹ mimọ́ ni.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 7