Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 7:13-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ati nigba keji Josefu fi ara rẹ̀ hàn fun awọn arakunrin rẹ̀; a si fi awọn ará Josefu hàn fun Farao.

14. Josefu si ranṣẹ, o si pè Jakọbu baba rẹ̀, ati gbogbo awọn ibatan rẹ̀ sọdọ rẹ̀, arundilọgọrin ọkàn.

15. Jakọbu si sọkalẹ lọ si Egipti, o si kú, on ati awọn baba wa,

16. A si gbe wọn lọ si Sikemu, a si tẹ́ wọn sinu ibojì ti Abrahamu rà ni iye-owo fadaka lọwọ awọn ọmọ Emoru baba Sikemu.

17. Ṣugbọn bi akokò ileri ti Oluwa ṣe fun Abrahamu ti kù si dẹ̀dẹ, awọn enia na nrú, nwọn si nrẹ̀ ni Egipti,

18. Titi ọba miran fi jẹ lori Egipti ti kò mọ̀ Josefu.

19. On na li o ṣe àrekerekè si awọn ibatan wa, nwọn si hùwa buburu si awọn baba wa, tobẹ̃ ti nwọn fi já awọn ọmọ-ọwọ wọn kuro lọwọ wọn nitori ki nwọn ki o máṣe yè.

20. Li akokò na li a bí Mose, ẹniti o li ẹwà pipọ, ti nwọn si bọ́ li oṣù mẹta ni ile baba rẹ̀:

21. Nigbati nwọn si gbe e sọnù, ọmọbinrin Farao he e, o si tọ́ ọ dàgba li ọmọ ara rẹ̀.

22. A si kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ará Egipti, o si pọ̀ li ọ̀rọ ati ni iṣe.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 7