Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 4:28-37 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Lati ṣe ohunkohun ti ọwọ́ rẹ ati imọ rẹ ti pinnu ṣaju pe yio ṣẹ.

29. Njẹ nisisiyi, Oluwa, kiyesi ikilọ wọn: ki o si fifun awọn ọmọ-ọdọ rẹ lati mã fi igboiya gbogbo sọ ọ̀rọ rẹ.

30. Ki iwọ si fi ninà ọwọ́ rẹ ṣe dida ara, ati ki iṣẹ àmi ati iṣẹ iyanu ki o mã ṣe li orukọ Jesu Ọmọ mimọ́ rẹ.

31. Nigbati nwọn gbadura tan, ibi ti nwọn gbé pejọ si mi titi; gbogbo wọn si kún fun Ẹmí Mimọ́, nwọn si nfi igboiya sọ ọ̀rọ Ọlọrun.

32. Ijọ awọn ti o gbagbọ́ si wà li ọkàn kan ati inu kan: kò si si ẹnikan ti o pè ohun kan ninu ohun ini rẹ̀ ni ti ara rẹ̀: ṣugbọn gbogbo nwọn ni gbogbo nkan ṣọkan.

33. Agbara nla li awọn aposteli si fi njẹri ajinde Jesu Oluwa; ore-ọfẹ pipọ si wà lori gbogbo wọn.

34. Nitori kò si ẹnikan ninu wọn ti o ṣe alaini: nitori iye awọn ti o ni ilẹ tabi ile tà wọn, nwọn si mu owo ohun ti nwọn tà wá.

35. Nwọn si fi i lelẹ li ẹsẹ awọn aposteli: nwọn si npín fun olukuluku, gẹgẹ bi o ti ṣe alaini si.

36. Ati Josefu, ti a ti ọwọ awọn aposteli sọ apele rẹ̀ ni Barnaba (itumọ̀ eyi ti ijẹ Ọmọ-Itùnu), ẹ̀ya Lefi, ati ara Kipru.

37. O ni ilẹ kan, o tà a, o mu owo rẹ̀ wá, o si fi i lelẹ li ẹsẹ awọn aposteli.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 4