Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 27:29-41 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. Nigbati nwọn bẹ̀ru ki nwọn ki o máṣe gbá lù ibi okuta, nwọn sọ idakọró mẹrin silẹ ni idi ọkọ̀, nwọn nreti ojumọ́.

30. Ṣugbọn nigbati awọn atukọ̀ nwá ọ̀na ati sá kuro ninu ọkọ̀, ti nwọn si ti sọ igbaja kalẹ si oju okun bi ẹnipe nwọn nfẹ sọ idakọró silẹ niwaju ọkọ̀,

31. Paulu wi fun balogun ọrún ati fun awọn ọmọ-ogun pe, Bikoṣepe awọn wọnyi ba duro ninu ọkọ̀ ẹnyin kì yio le là.

32. Nigbana li awọn ọmọ-ogun ke okùn igbaja, nwọn jọwọ rẹ̀ ki o ṣubu sọhún.

33. Nigbati ilẹ nmọ́ bọ̀, Paulu bẹ̀ gbogbo wọn ki nwọn ki o jẹun diẹ, o wipe, Oni li o di ijẹrinla ti ẹnyin ti nreti, ti ẹ kò dẹkun gbãwẹ, ti ẹ kò si jẹun.

34. Nitorina mo bẹ̀ nyin, ki ẹ jẹun diẹ: nitori eyi ni fun igbala nyin: nitori irun kan kì yio re kuro li ori ẹnikan nyin.

35. Nigbati o si wi nkan wọnyi, ti o si mu akara, o dupẹ lọwọ Ọlọrun niwaju gbogbo wọn: nigbati o si bù u, o bẹ̀rẹ si ijẹ.

36. Nigbana ni gbogbo wọn si daraya, awọn pẹlu si gbà onjẹ.

37. Gbogbo wa ti mbẹ ninu ọkọ̀ na si jẹ ọrinlugba ọkàn o dí mẹrin.

38. Nigbati nwọn jẹun yó tan, nwọn kó nkan danù kuro ninu ọkọ̀, nwọn si kó alikama dà si omi.

39. Nigbati ilẹ si mọ, nwọn kò mọ̀ ilẹ na: ṣugbọn nwọn ri apa odò kan ti o li ebute, nibẹ̀ ni nwọn gbero, bi nwọn o ba le tì ọkọ̀ si.

40. Nigbati nwọn si ké idakọró kuro, nwọn jọ̀wọ wọn sinu okun, lẹsẹkanna nwọn tu ide ọkọ̀, nwọn si ta igbokun iwaju ọkọ̀ si afẹfẹ, nwọn wa kọju si ilẹ.

41. Nigbati nwọn si de ibiti okun meji pade, nwọn fi ori ọkọ̀ sọlẹ; iwaju rẹ̀ si kàn mọlẹ ṣinṣin, o duro, kò le yi, ṣugbọn agbara riru omi bẹrẹ si fọ́ idi ọkọ̀ na.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 27