Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 27:21-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nigbati nwọn wà ni aijẹun li ọjọ pipọ, nigbana Paulu dide larin wọn, o ni, Alàgba, ẹnyin iba ti gbọ́ ti emi, ki a máṣe ṣikọ̀ kuro ni Krete, ewu ati òfo yi kì ba ti ba wa.

22. Njẹ nisisiyi mo gbà nyin niyanju, ki ẹ tújuka: nitori kì yio si òfo ẹmí ninu nyin, bikoṣe ti ọkọ̀.

23. Nitori angẹli Ọlọrun, ti ẹniti emi iṣe, ati ẹniti emi nsìn, o duro tì mi li oru aná,

24. O wipe, Má bẹ̀ru, Paulu; iwọ kò le ṣaima duro niwaju Kesari: si wo o, Ọlọrun ti fi gbogbo awọn ti o ba ọ wọkọ̀ pọ̀ fun ọ.

25. Njẹ nitorina, alàgba, ẹ daraya: nitori mo gbà Ọlọrun gbọ́ pe, yio ri bẹ̃ gẹgẹ bi a ti sọ fun mi.

26. Ṣugbọn a ó gbá wa jù si erekuṣu kan.

27. Ṣugbọn nigbati o di oru ijọ kẹrinla, ti awa ngbá sihin sọhún ni Adria, larin ọganjọ awọn atukọ̀ tànmã pe, awọn sunmọ eti ilẹ kan;

28. Nigbati nwọn si wọ̀n okun, nwọn ri i o jìn li ogún àgbaká: nigbati nwọn si sún siwaju diẹ, nwọn si tún wọ̀n okun, nwọn ri i o jìn ni àgbaká mẹ̃dogun.

29. Nigbati nwọn bẹ̀ru ki nwọn ki o máṣe gbá lù ibi okuta, nwọn sọ idakọró mẹrin silẹ ni idi ọkọ̀, nwọn nreti ojumọ́.

30. Ṣugbọn nigbati awọn atukọ̀ nwá ọ̀na ati sá kuro ninu ọkọ̀, ti nwọn si ti sọ igbaja kalẹ si oju okun bi ẹnipe nwọn nfẹ sọ idakọró silẹ niwaju ọkọ̀,

31. Paulu wi fun balogun ọrún ati fun awọn ọmọ-ogun pe, Bikoṣepe awọn wọnyi ba duro ninu ọkọ̀ ẹnyin kì yio le là.

32. Nigbana li awọn ọmọ-ogun ke okùn igbaja, nwọn jọwọ rẹ̀ ki o ṣubu sọhún.

33. Nigbati ilẹ nmọ́ bọ̀, Paulu bẹ̀ gbogbo wọn ki nwọn ki o jẹun diẹ, o wipe, Oni li o di ijẹrinla ti ẹnyin ti nreti, ti ẹ kò dẹkun gbãwẹ, ti ẹ kò si jẹun.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 27