Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 26:25-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Ṣugbọn Paulu wipe, Ori mi kò bajẹ, Festu ọlọlá julọ; ṣugbọn ọ̀rọ otitọ ati ti ìwa airekọja li emi nsọ jade.

26. Nitori ọba mọ̀ nkan gbogbo wọnyi, niwaju ẹniti emi nsọ̀rọ li aibẹ̀ru: nitori mo gbagbọ pe ọkan ninu nkan wọnyi kò pamọ fun u, nitoriti a kò ṣe nkan yi ni ìkọkọ.

27. Agrippa ọba, iwọ gbà awọn woli gbọ́? Emi mọ̀ pe, iwọ gbagbọ́.

28. Agrippa si wi fun Paulu pe, Pẹlu ọrọ iyanju diẹ si i, iwọ iba sọ mi di Kristiani.

29. Paulu si wipe, Iba wu Ọlọrun, yala pẹlu ãpọn diẹ tabi pipọ pe, ki o maṣe iwọ nikan, ṣugbọn ki gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ mi loni pẹlu le di iru enia ti emi jẹ laisi ẹwọn wọnyi.

30. Nigbati o si sọ nkan wọnyi tan, ọba dide, ati bãlẹ, ati Bernike, ati awọn ti o ba wọn joko:

31. Nigbati nwọn lọ si apakan, nwọn ba ara wọn sọ pe, ọkunrin yi kò ṣe nkankan ti o yẹ si ikú tabi si ẹ̀wọn.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 26