Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 25:15-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ẹniti awọn olori alufa ati awọn agbàgba awọn Ju fi sùn nigbati mo wà ni Jerusalemu nwọn nfẹ ki n da a lẹbi.

16. Awọn ẹniti mo si da lohùn pe, Kì iṣe iṣe awọn ara Romu lati da ẹnikẹni lẹbi, ki ẹniti a fisùn ki o to kò awọn olufisùn rẹ̀ loju, ki o si ri àye wi ti ẹnu rẹ̀, nitori ọ̀ran ti a kà si i lọrùn,

17. Nitorina nigbati nwọn jùmọ wá si ihinyi, emi kò jafara, nijọ keji mo joko lori itẹ́ idajọ, mo si paṣẹ pe ki a mu ọkunrin na wá.

18. Nigbati awọn olufisùn na dide, nwọn kò kà ọ̀ran buburu iru eyi ti mo rò si i lọrùn.

19. Ṣugbọn nwọn ni ọ̀ran kan si i, niti isin wọn, ati niti Jesu kan ti o ti kú, ti Paulu tẹnumọ́ pe o wà lãye.

20. Bi emi kò si ti mọ̀ bi a iti wadi nkan wọnyi, mo bi i lere bi o nfẹ lọ si Jerusalemu, ki a si ṣe ẹjọ nkan wọnyi nibẹ̀.

21. Ṣugbọn nigbati Paulu fi ọ̀ran rẹ̀ lọ Augustu, pe ki a pa on mọ fun idajọ rẹ̀, mo paṣẹ pe ki a pa a mọ titi emi o fi le rán a lọ sọdọ Kesari.

22. Agrippa si wi fun Festu pe, Emi pẹlu fẹ lati gbọ́ ọrọ ọkunrin na tikarami. O si wipe, Lọla iwọ o gbọ ọ.

23. Njẹ ni ijọ keji, ti Agrippa on Bernike wá, ti awọn ti ọsọ́ pipọ, ti nwọn si wọ ile ẹjọ, pẹlu awọn olori ogun, ati awọn enia nla ni ilu, Festu paṣẹ, nwọn si mu Paulu jade.

24. Festu si wipe, Agrippa ọba, ati gbogbo ẹnyin enia ti o wà nihin pẹlu wa, ẹnyin ri ọkunrin yi, nitori ẹniti gbogbo ijọ awọn Ju ti rọgbaká mi, ni Jerusalemu ati nihinyi, ti nwọn nkigbe pe, Kò yẹ fun u lati wà lãye mọ́.

25. Ṣugbọn emi ri pe, kò ṣe ohun kan ti o yẹ si ikú, bi on tikararẹ̀ si ti fi ọ̀ran rẹ̀ lọ Augustu, mo ti pinnu lati rán a lọ.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 25