Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 25:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ nigbati Festu de ilẹ na, lẹhin ijọ mẹta o gòke lati Kesarea lọ si Jerusalemu.

2. Awọn olori alufa ati awọn enia pataki ninu awọn Ju fi Paulu sùn u, nwọn si bẹ̀ ẹ,

3. Nwọn nwá oju're rẹ̀ si Paulu, ki o le ranṣẹ si i wá si Jerusalemu: nwọn ndèna dè e lati pa a li ọna.

4. Ṣugbọn Festu dahun pe, a pa Paulu mọ́ ni Kesarea, ati pe on tikara on nmura ati pada lọ ni lọ̃lọ̃yi.

5. O ni, njẹ awọn ti o ba to ninu nyin, ki nwọn ba mi sọkalẹ lọ, bi ìwa buburu kan ba wà lọwọ ọkunrin yi, ki nwọn ki o fi i sùn.

6. Kò si gbe ãrin wọn ju ijọ mẹjọ tabi mẹwa lọ, o sọkalẹ lọ si Kesarea; ni ijọ keji o joko lori itẹ́ idajọ, o si paṣẹ pè ki a mu Paulu wá.

7. Nigbati o si de, awọn Ju ti o ti Jerusalemu sọkalẹ wá duro yi i ká, nwọn nkà ọ̀ran pipọ ti o si buru si Paulu lọrùn, ti nwọn kò le ladi.

8. Paulu si wi ti ẹnu rẹ̀ pe, Emi kò ṣẹ ẹṣẹkẹṣẹ kan si ofin awọn Ju, tabi si tẹmpili, tabi si Kesari.

9. Ṣugbọn Festu nfẹ gbà oju're lọdọ awọn Ju, o si da Paulu lohùn, wipe, Iwọ ha nfẹ goke lọ si Jerusalemu, ki a si ṣe ẹjọ nkan wọnyi nibẹ̀ niwaju mi bi?

10. Paulu si wipe, Niwaju itẹ́ idajọ Kesari ni mo duro nibiti o yẹ ki a ṣe ẹjọ mi: emi kò ṣẹ awọn Ju, bi iwọ pẹlu ti mọ̀ daju.

11. Njẹ bi mo ba ṣẹ̀, ti mo si ṣe ohun kan ti o yẹ fùn ikú, emi kò kọ̀ lati kú: ṣugbọn bi kò ba si nkan wọnni ninu ohun ti awọn wọnyi fi mi sùn si, ẹnikan kò le fi mi ṣe oju're fun wọn. Mo fi ọ̀ran mi lọ Kesari.

12. Nigbana ni Festu lẹhin ti o ti ba ajọ igbìmọ sọ̀rọ, o dahùn pe, Iwọ ti fi ọ̀ran rẹ lọ Kesari: lọdọ Kesari ni iwọ ó lọ.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 25