Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 24:8-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. O paṣẹ ki awọn olufisùn rẹ̀ wá sọdọ rẹ: lati ọdọ ẹniti iwọ ó le ni oye gbogbo nkan wọnyi, nitori ohun ti awa ṣe fi i sùn nigbati iwọ ba ti wadi ẹjọ rẹ̀.

9. Awọn Ju pẹlu si fi ohùn si i, wipe, bẹ̃ni nkan wọnyi ri.

10. Nigbati bãlẹ ṣapẹrẹ si i pe ki o sọ̀rọ, Paulu si dahùn wipe, Bi mo ti mọ̀ pe lati ọdún melo yi wá, ni iwọ ti ṣe onidajọ orilẹ-ede yi, tayọtayọ ni ng o fi wi ti ẹnu mi.

11. Ki o le yé ọ pe, ijejila pére yi ni mo gòke lọ si Jerusalemu lati lọ jọsìn.

12. Bẹ̃ni nwọn kò ri mi ni tẹmpili ki emi ki o ma ba ẹnikẹni jiyàn, bẹ̃li emi kò rú awọn enia soke, ibaṣe ninu sinagogu, tabi ni ilu:

13. Bẹ̃ni nwọn kò le ladi ohun ti nwọn fi mi sùn si nisisiyi.

14. Ṣugbọn eyi ni mo jẹwọ fun ọ, pe bi Ọna ti a npè ni adamọ̀, bẹ̃li emi nsìn Ọlọrun awọn baba wa, emi ngbà nkan gbogbo gbọ́ gẹgẹ bi ofin, ati ti a kọ sinu iwe awọn woli:

15. Mo si ni ireti sipa ti Ọlọrun, eyi ti awọn tikarawọn pẹlu jẹwọ, pe ajinde okú mbọ̀, ati ti olõtọ, ati ti alaiṣõtọ.

16. Ninu eyi li emi si nṣe idaraya, lati ni ẹri-ọkàn ti kò li ẹ̀ṣẹ sipa ti Ọlọrun, ati si enia nigbagbogbo.

17. Ṣugbọn lẹhin ọdún pipọ, mo mu ọrẹ-ãnu fun orilẹ-ède mi wá, ati ọrẹ-ẹbọ.

18. Larin wọnyi ni nwọn ri mi ni iwẹnu ni tẹmpili, bẹ̃ni kì iṣe pẹlu awujọ, tabi pẹlu ariwo.

19. Ṣugbọn awọn Ju lati Asia wà nibẹ, awọn ti iba wà nihinyi niwaju rẹ, ki nwọn ki o já mi ni koro, bi nwọn ba li ohunkohun si mi.

20. Bi kò ṣe bẹ̃, jẹ ki awọn enia wọnyi tikarawọn sọ iṣe buburu ti nwọn ri lọwọ mi, nigbati mo duro niwaju ajọ igbimọ yi,

21. Bikoṣe ti gbolohùn kan yi, ti mo ke nigbati mo duro li ãrin wọn, Nitori ajinde okú li a ṣe ba mi wijọ lọdọ nyin loni yi.

22. Nigbati Feliksi gbọ́ nkan wọnyi, oye sa ye e li ayetan nipa Ọna na; o tú wọn ká na, o ni, Nigbati Lisia olori ogun ba sọkalẹ wá, emi o wadi ọ̀ran nyin daju.

23. O si paṣẹ fun balogun ọrún kan pe, ki o mã ṣe itọju Paulu, ki o si bùn u làye, ati pe ki o máṣe dá awọn ojulumọ̀ rẹ̀ lẹkun, lati ma ṣe iranṣẹ fun u.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 24