Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 24:2-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Nigbati a si ti pè e jade, Tertulu bẹ̀rẹ si ifi i sùn wipe, Bi o ti jẹ pe nipasẹ rẹ li awa njẹ alafia pipọ, ati pe nipasẹ itọju rẹ a nṣe atunṣe fun orilẹ yi.

3. Nigbagbogbo, ati nibigbogbo, li awa nfi gbogbo ọpẹ́ tẹwọgbà a, Feliksi ọlọla julọ.

4. Ṣugbọn ki emi ki o má bà da ọ duro pẹ titi, mo bẹ̀ ọ ki o fi iyọnu rẹ gbọ́ ọ̀rọ diẹ li ẹnu wa.

5. Nitori awa ri ọkunrin yi, o jẹ onijagidi enia, ẹniti o ndá rukerudo silẹ lãrin gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo aiye, ati olori ẹ̀ya awọn Nasarene:

6. Ẹniti o gbidanwo lati bà tẹmpili jẹ: ti awa si mu, ti awa fẹ ba ṣe ẹjọ gẹgẹ bi ofin wa.

7. Ṣugbọn Lisia olori ogun de, o fi agbara nla gbà a li ọwọ wa:

8. O paṣẹ ki awọn olufisùn rẹ̀ wá sọdọ rẹ: lati ọdọ ẹniti iwọ ó le ni oye gbogbo nkan wọnyi, nitori ohun ti awa ṣe fi i sùn nigbati iwọ ba ti wadi ẹjọ rẹ̀.

9. Awọn Ju pẹlu si fi ohùn si i, wipe, bẹ̃ni nkan wọnyi ri.

10. Nigbati bãlẹ ṣapẹrẹ si i pe ki o sọ̀rọ, Paulu si dahùn wipe, Bi mo ti mọ̀ pe lati ọdún melo yi wá, ni iwọ ti ṣe onidajọ orilẹ-ede yi, tayọtayọ ni ng o fi wi ti ẹnu mi.

11. Ki o le yé ọ pe, ijejila pére yi ni mo gòke lọ si Jerusalemu lati lọ jọsìn.

12. Bẹ̃ni nwọn kò ri mi ni tẹmpili ki emi ki o ma ba ẹnikẹni jiyàn, bẹ̃li emi kò rú awọn enia soke, ibaṣe ninu sinagogu, tabi ni ilu:

13. Bẹ̃ni nwọn kò le ladi ohun ti nwọn fi mi sùn si nisisiyi.

14. Ṣugbọn eyi ni mo jẹwọ fun ọ, pe bi Ọna ti a npè ni adamọ̀, bẹ̃li emi nsìn Ọlọrun awọn baba wa, emi ngbà nkan gbogbo gbọ́ gẹgẹ bi ofin, ati ti a kọ sinu iwe awọn woli:

15. Mo si ni ireti sipa ti Ọlọrun, eyi ti awọn tikarawọn pẹlu jẹwọ, pe ajinde okú mbọ̀, ati ti olõtọ, ati ti alaiṣõtọ.

16. Ninu eyi li emi si nṣe idaraya, lati ni ẹri-ọkàn ti kò li ẹ̀ṣẹ sipa ti Ọlọrun, ati si enia nigbagbogbo.

17. Ṣugbọn lẹhin ọdún pipọ, mo mu ọrẹ-ãnu fun orilẹ-ède mi wá, ati ọrẹ-ẹbọ.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 24