Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 24:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LẸHIN ijọ marun Anania olori alufa ni sọkalẹ lọ pẹlu awọn alàgba ati ẹnikan Tertulu agbẹjọrò ẹniti o fi Paulu sùn bãlẹ.

2. Nigbati a si ti pè e jade, Tertulu bẹ̀rẹ si ifi i sùn wipe, Bi o ti jẹ pe nipasẹ rẹ li awa njẹ alafia pipọ, ati pe nipasẹ itọju rẹ a nṣe atunṣe fun orilẹ yi.

3. Nigbagbogbo, ati nibigbogbo, li awa nfi gbogbo ọpẹ́ tẹwọgbà a, Feliksi ọlọla julọ.

4. Ṣugbọn ki emi ki o má bà da ọ duro pẹ titi, mo bẹ̀ ọ ki o fi iyọnu rẹ gbọ́ ọ̀rọ diẹ li ẹnu wa.

5. Nitori awa ri ọkunrin yi, o jẹ onijagidi enia, ẹniti o ndá rukerudo silẹ lãrin gbogbo awọn Ju ti o wà ni gbogbo aiye, ati olori ẹ̀ya awọn Nasarene:

6. Ẹniti o gbidanwo lati bà tẹmpili jẹ: ti awa si mu, ti awa fẹ ba ṣe ẹjọ gẹgẹ bi ofin wa.

7. Ṣugbọn Lisia olori ogun de, o fi agbara nla gbà a li ọwọ wa:

8. O paṣẹ ki awọn olufisùn rẹ̀ wá sọdọ rẹ: lati ọdọ ẹniti iwọ ó le ni oye gbogbo nkan wọnyi, nitori ohun ti awa ṣe fi i sùn nigbati iwọ ba ti wadi ẹjọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 24