Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 23:27-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Awọn Ju mu ọkunrin yi, nwọn si npete ati pa a: nigbana ni mo de pẹlu ogun, mo si gbà a lọwọ wọn nigbati mo gbọ́ pe ara Romu ni iṣe.

28. Nigbati mo si nfẹ mọ̀ idi ọ̀ran ti nwọn fi i sùn si, mo mu u sọkalẹ lọ si ajọ igbimọ wọn:

29. Ẹniti mo ri pe, nwọn fisùn nitori ọ̀ran ofin wọn, bẹ̃ni kò dà ọ̀ran kan ti o tọ́ si ikú ati si ìde.

30. Nigbati a si ti sọ fun mi pe, nwọn ó dèna dè ọkunrin na, ọgan mo si rán a si ọ, mo si paṣẹ fun awọn olufisùn rẹ̀ pẹlu, lati sọ ohun ti nwọn ba ri wi si i niwaju rẹ.

31. Nigbana li awọn ọmọ-ogun gbà Paulu, nwọn si mu u li oru lọ si Antipatri, gẹgẹ bi a ti paṣẹ fun wọn.

32. Nijọ keji nwọn si jọwọ awọn ẹlẹṣin lati mã ba a lọ, nwọn si pada wá sinu ile-olodi.

33. Nigbati nwọn de Kesarea, ti nwọn si fi iwe fun bãlẹ, nwọn mu Paulu pẹlu wá siwaju rẹ̀.

34. Nigbati o si ti kà iwe na, o bère pe ara ilẹ wo ni iṣe. Nigbati o si gbọ́ pe ara Kilikia ni;

35. O ni, Emi ó gbọ́ ẹjọ rẹ, nigbati awọn olufisùn rẹ pẹlu ba de. O si paṣẹ pe ki nwọn ki o pa a mọ́ ni gbọ̀ngan idajọ Herodu.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 23