Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 23:15-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Njẹ nisisiyi ki ẹnyin pẹlu ajọ igbimọ wi fun olori-ogun, ki o mu u sọkalẹ tọ̀ nyin wá, bi ẹnipe ẹnyin nfẹ wadi ọ̀ran rẹ̀ dajudaju: ki o to sunmọ itosi, awa ó si ti mura lati pa a.

16. Nigbati ọmọ arabinrin Paulu si gburó idena wọn, o lọ, o si wọ̀ inu ile-olodi lọ, o si sọ fun Paulu.

17. Paulu si pè ọkan ninu awọn balogun ọrún sọdọ rẹ̀, o ni, Mu ọmọkunrin yi tọ̀ olori-ogun lọ: nitori o ni nkan lati sọ fun u.

18. O mu u, o si sìn i lọ sọdọ olori-ogun, o si wipe, Paulu ondè pè mi sọdọ rẹ̀, o si bẹ̀ mi pe ki emi mu ọmọkunrin yi tọ̀ ọ wá, ẹniti o ni nkan lati sọ fun ọ.

19. Olori-ogun fà a lọwọ, o si lọ si apakan, o si bi i lere nikọkọ pe, Kili ohun ti iwọ ni isọ fun mi?

20. O si wipe, Awọn Ju fi ìmọ ṣọkan lati wá ibẹ̀ ọ ki o mu Paulu sọkalẹ wá si ajọ igbimọ li ọla, bi ẹnipe iwọ nfẹ bère nkan dajudaju nipa rẹ̀.

21. Nitorina máṣe gbọ́ tiwọn: nitori awọn ti o dèna dè e ninu wọn jù ogoji ọkunrin lọ, ti nwọn fi ara wọn bu pe, awọn kì yio jẹ, bẹ̃li awọn kì yio mu titi awọn o fi pa a: nisisiyi nwọn si ti mura tan, nwọn nreti idahùn lọdọ rẹ.

22. Nigbana li olori ogun jọwọ ọmọkunrin na lọwọ lọ, o si kìlọ fun u pe, Máṣe wi fun ẹnikan pe, iwọ fi nkan wọnyi hàn mi.

23. O si pè meji awọn balogun ọrún sọdọ rẹ̀, o si wipe, Ẹ mura igba ọmọ-ogun silẹ, lati lọ si Kesarea, ati adọrin ẹlẹṣin, ati igba ọlọkọ̀, ni wakati kẹta oru;

24. O si wipe, ki nwọn pèse ẹranko, ki nwọn gbé Paulu gùn u, ki nwọn si le mu u de ọdọ Feliksi bãlẹ li alafia.

25. O si kọ iwe kan bayi pe:

26. Klaudiu Lisia si Feliksi bãlẹ ọlọla julọ, alafia.

27. Awọn Ju mu ọkunrin yi, nwọn si npete ati pa a: nigbana ni mo de pẹlu ogun, mo si gbà a lọwọ wọn nigbati mo gbọ́ pe ara Romu ni iṣe.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 23