Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 22:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸNYIN ará, ati baba, ẹ gbọ ti ẹnu mi nisisiyi.

2. (Nigbati nwọn si gbọ́ pe o mba wọn sọrọ li ede Heberu, nwọn tubọ parọrọ; o si wipe,)

3. Ju li emi iṣe ẹniti a bí ni Tarsu ilu kan ni Kilikia, ṣugbọn ti a tọ́ ni ilu yi, li ẹsẹ Gamalieli, ti a kọ́ gẹgẹ bi lile ofin awọn baba wa, ti mo si jẹ onitara fun Ọlọrun ani gẹgẹ bi gbogbo nyin ti ri li oni.

4. Mo si ṣe inunibini si Ọna yi titi o fi de iku, mo ndè, mo si nfi wọn sinu tubu, ati ọkunrin ati obinrin.

5. Bi olori alufa pẹlu ti jẹ mi li ẹri, ati gbogbo ajọ awọn alàgba: lọwọ awọn ẹniti mo si gbà iwe lọ sọdọ awọn arakunrin, ti mo si lọ si Damasku lati mu awọn ti o wà nibẹ̀ ni didè wá si Jerusalemu, lati jẹ wọn niyà.

6. O si ṣe, bi emi ti nlọ, ti mo si sunmọ eti Damasku niwọn ọjọkanri, li ojijì, imọlẹ nla mọ́ ti ọrun wá yi mi ká.

7. Mo si ṣubu lùlẹ, mo si ngbọ́ ohùn kan ti o wi fun mi pe, Saulu, Saulu, ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi?

8. Emi si dahùn wipe, Iwọ tani, Oluwa? O si wi fun mi pe, Emi Jesu ti Nasareti ni, ẹniti iwọ nṣe inunibini si.

9. Awọn ti o si wà pẹlu mi ri imọlẹ na nitõtọ, ẹ̀ru si ba wọn; ṣugbọn nwọn kò gbọ́ ohùn ẹniti mba mi sọrọ.

10. Mo si wipe, Kini ki emi ki o ṣe, Oluwa? Oluwa si wi fun mi pe, Dide, ki o si lọ si Damasku; nibẹ̀ li a o si sọ ohun gbogbo fun ọ ti a yàn fun ọ lati ṣe.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 22