Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 20:30-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. Ati larin ẹnyin tikaranyin li awọn enia yio dide, ti nwọn o ma sọ̀rọ òdi, lati fà awọn ọmọ-ẹhin sẹhin wọn.

31. Nitorina ẹ mã ṣọra, ki ẹ si mã ranti pe, fun ọdún mẹta, emi kò dẹkun ati mã fi omije kìlọ fun olukuluku li ọsán ati li oru.

32. Njẹ nisisiyi, ará, mo fi nyin le Ọlọrun lọwọ ati ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, ti o le gbe nyin duro, ti o si le fun nyin ni ini lãrin gbogbo awọn ti a sọ di mimọ́.

33. Emi kò ṣe ojukòkoro fadaka, tabi wura, tabi aṣọ ẹnikẹni.

34. Ẹnyin tikaranyin sá mọ̀ pe, ọwọ́ wọnyi li o ṣiṣẹ fun aini mi, ati ti awọn ti o wà pẹlu mi.

35. Ninu ohun gbogbo mo fi apẹrẹ fun nyin pe, nipa ṣiṣe iṣẹ bẹ̃, yẹ ki ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ki ẹ si mã ranti ọ̀rọ Jesu Oluwa, bi on tikararẹ̀ ti wipe, Ati funni o ni ibukún jù ati gbà lọ.

36. Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, o kunlẹ, o si ba gbogbo wọn gbadura.

37. Gbogbo wọn si sọkun gidigidi, nwọn si rọ̀ mọ́ Paulu li ọrùn, nwọn si fi ẹnu kò o li ẹnu,

38. Inu wọn si bajẹ julọ fun ọ̀rọ ti o sọ pe, nwọn kì yio ri oju on mọ́. Nwọn si sìn i lọ sinu ọkọ̀.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 20