Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 20:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI ariwo na si rọlẹ, Paulu ranṣẹ pè awọn ọmọ-ẹhin, o si gbà wọn ni iyanju, o dagbere fun wọn, o dide lati lọ si Makedonia.

2. Nigbati o si ti là apa ìha wọnni kọja, ti o si ti fi ọ̀rọ pipọ gbà wọn ni iyanju, o wá si ilẹ Hellene.

3. Nigbati o si duro nibẹ̀ li oṣù mẹta, ti awọn Ju si dèna dè e, bi o ti npete ati ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, o pinnu rẹ̀ lati ba ti Makedonia pada lọ.

4. Sopateru ara Berea ọmọ Parru si ba a lọ de Asia; ati ninu awọn ara Tessalonika, Aristarku on Sekundu; ati Gaiu ara Derbe, ati Timotiu; ati ara Asia, Tikiku on Trofimu.

5. Ṣugbọn awọn wọnyi ti lọ ṣiwaju, nwọn nduro dè wa ni Troa.

6. Awa si ṣikọ̀ lati Filippi wá lẹhin ọjọ aiwukara, a si de ọdọ wọn ni Troasi ni ijọ karun; nibiti awa gbé duro ni ijọ meje.

7. Ati ni ọjọ ikini ọ̀sẹ nigbati awọn ọmọ-ẹhin pejọ lati bù akara, Paulu si wasu fun wọn, o mura ati lọ ni ijọ keji: o si fà ọ̀rọ rẹ̀ gùn titi di arin ọganjọ.

8. Fitilà pipọ si wà ni yàrá oke na, nibiti a gbé pejọ si.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 20