Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 2:6-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nigbati nwọn si gbọ iró yi, ọ̀pọlọpọ enia pejọ, nwọn si damu, nitoriti olukuluku gbọ́ nwọn nsọ̀rọ li ède rẹ̀.

7. Hà si ṣe gbogbo wọn, ẹnu si yà wọn, nwọn nwi fun ara wọn pe, Wo o, ara Galili ki gbogbo awọn ti nsọ̀rọ wọnyi iṣe?

8. Ẽha si ti ṣe ti awa fi ngbọ́ olukuluku li ede wa ninu eyiti a bí wa?

9. Awọn ará Partia, ati Media, ati Elamu, ati awọn ti ngbé Mesopotamia, Judea, ati Kappadokia, Pontu, ati Asia,

10. Frigia, ati Pamfilia, Egipti, ati ẹkùn Libia niha Kirene, ati awọn atipo Romu, awọn Ju ati awọn alawọṣe Ju,

11. Awọn ara Krete ati Arabia, awa gbọ́ nwọn nsọ̀rọ iṣẹ iyanu nla Ọlọrun li ède wa.

12. Hà si ṣe gbogbo wọn, o si rú wọn lojú, nwọn wi fun ara wọn pe, Kili a le mọ̀ eyi si?

13. Ṣugbọn awọn ẹlomiran nṣẹ̀fẹ nwọn si wipe, Awọn ọkunrin wọnyi kún fun waini titun.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 2