Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 2:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI ọjọ Pentekosti si de, gbogbo nwọn fi ọkàn kan wà nibikan.

2. Lojijì iró si ti ọrun wá, gẹgẹ bi iró ẹ̀fũfu lile, o si kún gbogbo ile nibiti nwọn gbé joko.

3. Ẹla ahọn bi ti iná si yọ si wọn, o pin ara rẹ̀ o si bà le olukuluku wọn.

4. Gbogbo nwọn si kún fun Ẹmí Mimọ́, nwọn si bẹ̀rẹ si ifi ède miran sọrọ, gẹgẹ bi Ẹmí ti fun wọn li ohùn.

5. Awọn Ju olufọkànsin lati orilẹ-ede gbogbo labẹ ọrun si ngbe Jerusalemu.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 2