Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Iṣe Apo 17:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI nwọn si ti kọja Amfipoli ati Apollonia, nwọn wá si Tessalonika, nibiti sinagogu awọn Ju wà:

2. Ati Paulu, gẹgẹbi iṣe rẹ̀, o wọle tọ̀ wọn lọ, li ọjọ isimi mẹta o si mba wọn fi ọ̀rọ we ọ̀rọ ninu iwe-mimọ́,

3. O ntumọ, o si nfihàn pe, Kristi kò le ṣaima jìya, ki o si jinde kuro ninu okú; ati pe, Jesu yi, ẹniti emi nwasu fun nyin, on ni Kristi na.

4. A si yi ninu wọn lọkàn pada, nwọn si darapọ̀ mọ́ Paulu on Sila; ati ninu awọn olufọkansìn Hellene ọ̀pọ pupọ, ati ninu awọn obinrin ọlọlá, kì iṣe diẹ.

5. Ṣugbọn awọn Ju jowu, nwọn si fà awọn jagidijagan ninu awọn ijajẹ enia mọra, nwọn gbá ẹgbẹ jọ, nwọn si nrú ilu; nwọn si kọlù ile Jasoni, nwọn nfẹ mu wọn jade tọ̀ awọn enia wá.

6. Nigbati nwọn kò si ri wọn, nwọn wọ́ Jasoni, ati awọn arakunrin kan tọ̀ awọn olori ilu lọ, nwọn nkigbe pe, Awọn wọnyi ti o ti yi aiye po wá si ihinyi pẹlu;

7. Awọn ẹniti Jasoni gbà si ọdọ: gbogbo awọn wọnyi li o si nhuwa lodi si aṣẹ Kesari, wipe, ọba miran kan wà, Jesu.

8. Awọn enia ati awọn olori ilu kò ni ibalẹ aiya nigbati nwọn gbọ́ nkan wọnyi.

9. Nigbati nwọn si gbà ogò lọwọ Jasoni ati awọn iyokù, nwọn jọwọ lọ.

10. Lọgan awọn arakunrin si rán Paulu on Sila lọ si Berea li oru: nigbati nwọn si de ibẹ̀, nwọn wọ̀ inu sinagogu awọn Ju lọ.

11. Awọn wọnyi si ni iyìn jù awọn ti Tessalonika lọ, niti pe nwọn fi tọkantọkan gbà ọ̀rọ na, nwọn si nwá inu iwe-mimọ́ lojojumọ́ bi nkan wọnyi ri bẹ̃.

12. Nitorina pipọ ninu wọn gbagbọ́; ati ninu awọn obinrin Hellene ọlọlá, ati ninu awọn ọkunrin, kì iṣe diẹ.

13. Ṣugbọn nigbati awọn Ju ti Tessalonika mọ̀ pe, Paulu nwasu ọ̀rọ Ọlọrun ni Berea, nwọn si wá sibẹ̀ pẹlu, nwọn rú awọn enia soke.

Ka pipe ipin Iṣe Apo 17